Brexit: Ǹkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU

Awon eniyan ni papko ofurufu ti wọ́n wa fun apero EU

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo ọmọ ilẹ gẹẹsi naa ni wan o si ma ṣe bi ara EU titi ti isipo padfa yoo fi pari
    • Author, Tom Edgington
    • Role, BBC News Analysis

Lẹ́yin ọdun mẹta lílọ bibọ lori ọ̀rọ̀ Brexit, ilẹ Gẹẹsi pada kúrò labẹ EU ni ààgo mọkànla alẹ ojọ Jimọ ọjọ kọkanlelọ́gbọ̀n oṣù kini ọdun 2020.

Láàrin yìí ilẹ̀ Gẹẹsi yóò si maa tèlé àwọn òfin EU bákan náà ni wọ́n a maa san owó ti o yẹ. Awọn ǹkan yóò jọra wọ́n sùgbọ́n àwọn míràn yóò maa yi pada.

1.Gbogbo àwọn asoju igbimọ asofin ilẹ Gẹẹsi yóò pàdanu ààye wọ́n ni EU

Nigel Farage sàjọyọ iyansipo tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nigel Farage's to jẹ asoju Brexit lo gba ọpọ ààye ilẹ Gẹẹsi ni EU lọdun 2019

Adari ẹgbẹ́ Brexit, Nigel Farage jẹ́ ọkàn lára àwọn agbatẹru to ni pe ki Uk fi EU silẹ naa si jẹ ọkan ninu àwọn asoju mẹ́taleláàdọrin ti yóò padanu ààye wọn ni ilé Asofin Yuropu.

Eyi tumọ si pe lọ́wọ́lọ́wọ́ ilẹ Gẹẹsi yóò fi gbogbo ètò òṣèlú àti àwọn àjọ to jẹ ti EU silẹ

2.Ko si aperò European Union mọ

Asoju ijọba ilẹ Gẹẹsi Boris Johnson yoo ni lati gba ìwé ìpe ko to yoju sibi àpero EU lọ́jọ iwáju.

Bakan náà àwọn mínísita ilẹ Gẹẹsi ko ni le peju sibi àpero to ni ṣe pẹlu ètò kankan.

3. A o maa gbọ ǹkan ti o pọ̀ nipa òwò

Ilẹ Gẹẹsi yoo le ma ba àwọn orilẹ-èdè miran lágbàye sọ̀rọ̀ nipa nipa ilàna tuntun lóri kátakara.

Sáàju àsìkò yìí UK ko ni ànfani lati se àdehun ìdokoowo pẹlu orilẹ-èdè miran bi US àti Australia ṣe n se, lásiko ti wọ́n wa lábẹ EU.

Eyi si jẹ ọkan ninu ìdí ti wọ́n fi kuro ni EU , nitori won fẹ́ ni òòre-ọ̀fẹ láti ṣe ǹkan wọ́n fun ara wọ́n.

Ti won ba ti ẹ lu aluyọ lati doko-owo pẹlu orilẹ̀-èdè kan, wọ́n ko ni le se titi ti àsìkò ti won yoo fi kuor ni EU patapata

4. Ìwé ìrìna UK yoo paarọ àwọ

British passports
Àkọlé àwòrán, Ni ọdun 1988 iwe irina alawọ bulu di àwo lawọ pupa fẹẹrẹ

Ìwé ìrìnà àlàwọ omí aro yóò pada wá lẹ́yin ọgbọ̀n ọdun ti wọ́n ti yii pada si àwọ ti wọ́n n lò lọ́wọ́ báyìí.

Ìpolongo yìí wáye lọ́dun 2017 láti pada si alawo bulu ti wọ́n lo ni ọdun 2021.

5. Owó Brexit

Sajid Javid with the new coin

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Atunse yóò ba owó lẹ́yin Brexit

O to mílíọnu mẹta owo brexit ti wọ́n kọ deeti ọjọ kọkanlelọgbọ̀n osu kini le lóri ti wọ́n si ko akole "Peace, prosperity and friendship with all nations", yoo bẹ̀rẹ̀ si ni di nína ni ọjọ Jimọ.

Ọ̀pọ̀ lo ti tako owo náà ti wọ́n si i àwọn ko fọ́wọ́ si.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn owo ẹyọ náà ni wọ́n ti dá pada, ti wọ́n si ti fi ṣe ǹkan míran miran lẹ́yin ti àsìkò ti wọ́n da ti kọja

6. Ẹ̀ka Brexit ti pari ojúse wọ́n, abala náà yoo kógbá silé

Àwọn ìgbìmọ̀ to moju to bi ilẹ gẹṣi sẹ lo si Brexit ti di tituka lánàá.

Ẹ̀ka to moju to kikuro ni EU ti asoju ijọba tẹlẹ Theresa May dá silẹ lọ́dun 2016 na yoo kuro nipò

Ti àpero kankan ba jẹyọ lọ́jọ́ iwáju àwon alagbàwi UK yoo ma fi Downing Street ṣe olu ile iṣẹ́ wọ́n.

7. Orilẹ̀-èdè Germany ko ni fi àwọn ọdànran ranṣẹ́ si UK

kò ní ṣeeṣe fun àwọn ọdanran kan láti pada si UK ti wọ́n ba ti fi igba kan sa lọ si Germany tẹlẹ.

Orilẹ-èdè Germany kii gba ki wọ́n mu ọmọ ilú rẹ̀ lọ si orilẹ̀-èdè to ba yàtọ si èyi to wà lábẹ EU.

Ko ti dáju boya ìru rẹ naa le ṣẹlẹ si àwọn ọmọ orilẹ̀-èdè míran bii Slovania.

Nítori pe ìsípò pada ilẹ Gẹẹsi bẹ̀rẹ̀ loni wàrànsesà, àwọn àkan miran ko ni yí pada, o kéré tan titi di inú oṣù kejila ọddun 2020.

1. Irin Ajo

Awon eniyan ni papko ofurufu ti wọ́n wa fun apero EU

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo ọmọ ilẹ gẹẹsi naa ni wan o si ma ṣe bi ara EU titi ti isipo padfa yoo fi pari

Ọkọ ofurufu àti reluwe yóò ma ṣe iṣẹ́ bi o ṣe n ṣe tẹ́lẹ̀.

Lásìkò ìsípò pada , àwọn ilẹ̀ Gẹẹsi yoo si ma to si ibi ti wọ́n pèsè fun àwọn ọmọ EU nikan

2. Ìwé ìwak, ìwé nini ǹkan ọ̀sin

Níwọ̀n ìgbà ti o ba ti jẹ́ pe ko ti lùgbàdi àkókò

3. Kaadi European Health Insurance (EHIC)

owo to di kaadi mu

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán, Kaadi idanimo ti won fi gba itojubni EU

Kaadi yii ni wọ́n ma fi ngba itoju yala ti eniyan ba ṣe aisan tabi wọ́n ni ijamba kan tabi omiran

Wọ́n le lo ni orilẹ̀-èdè to ba wa ni abẹ EU, ni Switzerland, Norway, Iceland àti Liechtenstein, eyi yoo si maa siṣẹ́ lọ titi wọ́n yoo fi sípò pada tan.

4. Wọ́n le maa siṣẹ́ ki wọ́n maa gbe ni EU

Ominira wà fun láti yan si ibi to ba wù wọ́n lásìkò ìsípò pada, àwọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi yoo si ni ànfani lati ma gbe ti wan o si ma ṣiṣẹ́ ni EU bi an ṣe nṣe tẹ́lẹ̀

Bakan náà ni yoo si ṣe ri fun ọmọ EU kankan to ba fẹ láti ma ṣiṣẹ́ tàbi gbe ni UK

5. Owó ìfẹyinti

Àwọ̀n ọmọ ilẹ̀ Gẹẹsi to ngbé ni EU yoo si maa gba owó ìfẹyinti wọ́n lọ bẹẹni wọ́n yoo ma gba àwọn ajẹmọnu to ba n gu ori rẹ lọdọọdun

6. Dídáwo si ìsúna EU

Títí ti wọ́n yóò fi pari ètò ìsípò pàda, Uk yóò si ma da owó si àpò ìsúna EU. Itumọ eyi ni pe àdehun to ti wà nilẹ tẹlẹ lati maa dáwọ si ètò kan to wà nile tẹlẹ o ni yẹ.

7. Òwò ṣíṣe

Idokoowo UK àti EU yoo si wà bo ṣe wa lai ni àfikun àwọn owo kankan ninu