Coronavirus: Ọmọ ilẹ̀ China kan ti kú sí orílẹ́èdè míì lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ to n ri si eto ilera lorilẹede Naijiria ni pẹlu ajọṣepọ ajọ agbaye to n ri si eto ilera WHO, Naijiria ti ni ibudo to lee kapa ṣiṣe ayẹwo ẹni to ba ko aarun aṣekupani Coronavirus eyi to bẹrẹ lorilede China.
Minisita wa lo oju opo itakun Twitter wọn lati fun pe si ẹnikẹni lorilede Naijira to ti lọ si China ni oṣu bii melo sẹyin lati "ya ara wọn s'ọ́tọ̀ na fun ọjọ́ mẹ́rìnlá ki wọn si pe ajọ to nṣamojuto kikoju aarun NCDC lori nọmba 07032864444.

Oríṣun àwòrán, @Fmohnigeria
Bakan naa wọn tẹnu mọ ọ pé ẹnikẹni to ba ti ri i pe oun ni iba, ikọ, ọna ọfun n dun un ati inira lati mí, ki o tete lọ si ileewosan to ba wa ni tosi rẹ.
Ehanire gba gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto ilera niyanju pe bi wọn ba ṣe n tọju awọn to ba wa, ki wọn maa fun wọn ni iboju, ki wọn si ya wọn sọtọ ki wọn to kan si ajọ NCDC.
O ti le lọdunrun-un eeyan to ti dero ọrun bayii nipasẹ aarun coronavirus eyi ti ọpọ ninu wọn wa lati ẹkun Hubei ni Wuhan.
- 'Èmi tí mo gé lápá àti ẹsẹ̀ náà ló máa ń wá ọ̀rọ̀ sọ fún èèyàn kí wọ́n má baà sá fún mi'
- Atiku banújẹ́ sí ìròyìn pé Amẹ́ríkà dínà mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Jégéjégé la ó rún ọ̀kàdà àti kẹ̀kẹ́ Maruwa tí a bá mú l'Eko- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Báyìí ni ìgboro Eko ṣe rí lẹ́yìn tí ìjọba fòfin de Keke àti Okada
- Ọmọ ìjọ 20 kú bí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n pa níbi ìsọjí ìtagbangba
Ọmọ ilẹ̀ China kan ti kú sí orílẹ́èdè míì lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn náà
Ọkunrin kan ti gbẹmi mi lorilẹede Philippines lẹyin to lugbadi aarun Coronavirus to n ran kaakiri agbaye bayii.
Ọmọ orilẹede China ni ọkunrin naa, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, ọmọ ilu Wuhan to wa lẹkun Hubei ti aarun Coronavirus ti bẹrẹ ni ọkunrin naa ti wa.
Ajọ to n ri si eto ilera lagbaaye, WHO ṣalaye pe o dabi ẹni pe ọkunrin naa ti lugbadi aarun Coronavirus ko to rinrin ajo lọ si orilẹede Philippines.
- Corovavirus: Àjọ WHO tí bẹ̀rẹ̀ ètò láti ran àwọn orílẹ́-èdè Afrika lọ́wọ́
- Awọn ikọ BBC ṣe abẹwo si China nibi ti aarun Coronavirus ti n ja rain
- Ìdí tí Ààrẹ Trump fi dínà mọ́ Nàìjíríà àtí orílẹ̀èdè márùn ún míì láti má wọ Amẹ́ríkà
- Ọkọ̀ wa wọ'gbó lọ lẹ́yìn táwọn dánàdánà dàbọn bò wá- Toyosi Adesanya
- Àgbékalẹ̀ Amotekun dára torí agbára òògùn àwọn baba wa kò dínkù tàbí parẹ́ - Peter Fatomilola
- Brexit: Ǹkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU
- Báyìí ni ìgboro Eko ṣe rí lẹ́yìn tí ìjọba fòfin de Keke àti Okada
O ti le lọdunrun un eeyan to ti dero ọrun bayii nipasẹ aarun coronavirus eyi ti ọpọ ninu wọn wa lati ẹkun Hubei ni Wuhan ti aarun naa ti bẹrẹ.
Eeyan to le lẹgbẹrun un mẹrinla lo ti ni aarun coronavirus bayii kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, ọrọ di bo o lọ, o ya a mi nile iwosan kan ni Wuse niluu Abuja lọjọ Abamẹta lẹyin tawọn eeyan marun un kan parọ pe awọn ti ko aarun coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eeyan naa ti orukọ wọn jẹ Peggy Shandi, Abayomi Adedoyin, David Enemigin, Priscilla Ajesola ati Jacob Oji ṣe idiwọ fun ilera nile iwosan naa.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa l'Abuja, DSP Anjuguri Manza ṣalaye pe awọn eeyan naa yoo foju ba ileẹjọ ẹjọ lẹyin tawọn agb ofinro ba pari iṣẹ iwadii wọn tan.

Akọwe iroyin fun minisita olu ilu Naijiria, Ọgbẹni Anthony Ogunleye sọ ninu atẹjade kan pe oludari eto ilera niluu Abuja, Dokita Josephine Okechukwu ti fọkan awọn ara ilu Abuja balẹ pe ko si ohun to jọ aarun coronavirus l'Abuja.












