Hannah Olateju: Nigba miiran, ọkan awọn eeyan kii balẹ lati wa pẹlu mi

Àkọlé fídíò, 'Èmi tí mo gé lápá àti ẹsẹ̀ náà ló máa ń wá ọ̀rọ̀ sọ fún èèyàn kí wọ́n má baà sá fún mi'

Ninu fidio oke yii, ọmọ ogún ọdún ni Hannah Olateju to jẹ ẹni to ge lapa ati ẹṣẹ ṣugbọn irinisi rẹ ko lee fun un yin lanfani ati foju tẹmbẹlu rẹ tabi wo o tika tẹ̀gbin.

Hannah ni nigba toun wa lọmọ ọdun meji ni oun ti kọkọ ni aisan yinrunyinrun ṣugbọn nigba yẹn gan oun a maa jẹ ọmọ oninu didun.

"Mo rántí bí mo ṣe máa ń sá kiri bí adìyẹ ní kékeré, mo ní ìgboyà mo sì dá ara mi lójú".

Àkọlé fídíò, Èyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀

Gbajugbaja ni Hannah jẹ́ lori ayelujara eyi tumọ si wi pe ko tilẹ tiju ipo to wa rara debi ti yoo jẹ ko di i lọwọ ohun to lee da laye.

"Àwọn èèyàn kìí mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ sí ẹni tó gé lápá, lẹ́sẹ̀ bí èmi. Bí mo tilẹ̀ gé lápá àti ẹsẹ, èmi ni mo máa ń kí àwọn èèyàn láti fihàn pé ǹkan ń lọ dáadáa".

Hannah fọwọ sọya sọ wi pe "ìyàtọ̀ tó kàn wà láàrin èmi àtiyín ni pé ẹsẹ̀ àti ọwọ́ tiyín ju tèmi lọ".