Pastor Adeboye ṣáájú ìwọ́de àdúrà lòdí sí ìpànìyàn ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @rccg_pr
Jakejado orilẹede Naijiria lowurọ yii ni ijọ irapada ti gbogbo eniyan mọ si Redeemed Christian Church of God ṣe iwọde ifẹhonu han lodi si iṣekupani to n di lemolemo lorilede Naijiria.
Laipẹ yii ni awọn ajinigbe ṣekupa alaga ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni iha Guusu Naijiria. Eyi ati ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijira to n la ijinigbe ati iṣekupani kọja lo mu ki ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lapapọ lorilede Naijira kede iwọde yii.

Oríṣun àwòrán, Isaac Jeremiah

Pasitọ ijọ Redeem, Enoch Adejare Adeboye nibi isin idupẹ oṣu keji ọdun eyi to waye ni iya ijọ Redeem to wa ni Ebute Meta, ipinlẹ Eko sọ wi pe "gbogbo ẹni ti wọn pa lorilẹede Naijiria yala Kristẹni tabi Musulumi gbudọ ṣe pataki si wa".

Oríṣun àwòrán, @yemility007
Lẹyin ti Adeboye le adura fun aabo, ipamọ ati alafia fun orilẹede Naijiria ninu isin naa tan lo mẹnu ba ọrọ awọn ti wọn n ṣekupa lorilẹede yii.
Latari eyi oni ẹgbẹ CAN ti kede pe ki gbogbo Kristẹni ṣe iwọde lodi si i eyi to pe ni "irin adura(prayer walk)".
Ninu iwọde ọhun, Pasitọ Adeboye lo ṣaaju awọn ọmọ ijọ rẹ pẹlu patako ti wọn gbe lọwọ pẹlu akọle to sọ wi pe "Gbogbo kan se iyebiye si Ọlọrun".

Oríṣun àwòrán, RCCG Abba Father, Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, Isaac Jeremaih
- A ti gbáradì báyìí pẹ̀lú ibùdó tó lèé kápáa àyẹ̀wò ààrùn Coronavirus - Ileéṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà
- Jégéjégé la ó rún ọ̀kàdà àti kẹ̀kẹ́ Maruwa tí a bá mú l'Eko- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Atiku banújẹ́ sí ìròyìn pé Amẹ́ríkà dínà mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà
- 'Èmi tí mo gé lápá àti ẹsẹ̀ náà ló máa ń wá ọ̀rọ̀ sọ fún èèyàn kí wọ́n má baà sá fún mi'
- Ọmọ ìjọ 20 kú bí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n pa níbi ìsọjí ìtagbangba

Oríṣun àwòrán, RCCG Jesus House

Oríṣun àwòrán, RCCG TEAP, Abuja









