Atiku sí America: Ẹ má fìyà ìjọba tó ń kùnà jẹ àwọn ọmọ Nàijíríà

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @atiku

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ṣe gbe ote le lilọ si Amẹrikaa awọn ọmọ Naijiria lati lọ maa gbe nibẹ ti n da ori ayelujara laamu.

Ko wa duro nibi igbesẹ orilede Amẹrika nikan o, awọn eekan ni Naijiria da si ọrọ naa. Ẹwẹ, ni lọọlọ yii, ohun ti Alhaji Atiku Abubakar sọ lo n gbe awọn eeyan ninu ju.

Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri ati oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2019 fesi loju opo Twitter rẹ pe oun gba iroyin ibanujẹ pe aarẹ Donald Trump bẹgi dina wiwa awọn ọmọ Naijiria si orilẹede Amẹrika.

Atiku kọ oniruuru ọrọ ati ero ọkan rẹ silẹ leyi ti awọn ọmọ Naijiria naa si gbọn ọn yẹbẹ lati sọ idi ti wọn fi ni ọrọ rẹ mu ọpọlọ dani fawọn tabi ta ko ohun to sọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lori ti pe o banujẹ, awọn kan da a lohun pe ki lo kan pẹlu ti ibanujẹ wi pe ṣe bi Naijiria naa lee ṣe ohun ti Amẹrika ṣe fun awọn ọmọ ibẹ naa ti Naijiria si le da gbe lai ni wọn laarin awọn.

Bẹẹ ni ẹlomiran tun fesi pe ki lo kan an niwọn igba ti Atiku funra rẹ kii ṣe ọmọ orilẹede Naijiria.

Esi si ọrọ Atiku

Oríṣun àwòrán, @atiku

Bi awọn to ta ko o ṣe n sọ tiwọn naa ni awọn mii n sọ wipe ki ba wu awọn ko jẹ pe lori eyi, aarẹ Buhari kọ ni aarẹ Naijiria.

Ayò Bánkólé ni bi ẹ ba tilẹ korira Atiku, ẹ o gbudọ ma fẹran iru esi to fọ yii. O ni oun ti fẹ sọ pe iru adari ti a fẹ leleyii ṣugbọn oun tun ranti pe ẹgbẹ oṣelu APC naa maa n sọ ọrọ ọlọgbọn tẹlẹ ki wọn to ko wọ inu Aso Rock ti ohun gbogbo si yi biri.

Esi si ọrọ Atiku

Oríṣun àwòrán, @atiku

Mighty Wiglaf ni "mo sọ fun gbogbo yin pe ọkunrin yii ni ko ṣe daadaa gẹgẹ bi aarẹ wa ṣugbọn ko sẹni to gba mi gbọ ninu yin".

Esi si ọrọ Atiku

Oríṣun àwòrán, @KvngLerry

Ẹwẹ, ile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Amẹrika ti ni awọn yoo ṣe agbekalẹ abadofin "ma dina mọ ẹnikẹni" lodi si igbesẹ ti aarẹ Donald Trump gbe.

Bi o tilẹ jẹ pe ote ti aarẹ Trump gbe le irina wọ ilẹ Amẹrika yii ko ba ti ẹni to ba wa ṣe iṣẹ wi, oniṣowo, igbafẹ ati ọmọ ile iwe wi.

Adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Nancy Pelosi ni igbes aarẹ Trump yii foju keree ipo adari ti US wa lagbaye, ofin ati bi nkan ṣe ti wa nilẹ tẹlẹ.

Pelosi ni ile igbimọ maa to ṣe agbekalẹ ofin ti yoo din agbara ti aarẹ ni ku lati gbe iru igbesẹ to fi sibi kan yii nipa didina mọ awọn ọmọ orilede kan lati ma le wọ Amẹrika.