Atiku: N36m ni àwọn kan ń tọrọ fún mi láì mọ̀ lórí ayélujára

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ti kede faraye pe oun ko mọwọ tabi mẹsẹ ninu ikede agbe sise ti awọn eeyan kan n se fun oun lori itakun agbaye.

Atiku ni agbe ti wọn tẹ pẹpẹ rẹ naa ni wọn sọ pe o wa lati se atilẹyin fun oun lori ẹjọ ti oun pe lati tako esi ibo aarẹ, ti Muahammadu Buhari bori.

Nigba to n fesi si ọrọ yii, ọgbẹni Phrank Shaibu tii se agbẹnusọ fun Atiku lori eto ibaraẹnisọrọ ati aabo ni ko si ohunkohun to kan Atiku ninu bara ori itakun agbaye naa, eyi to ti n fa ariyanjiyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Afojusun ati oju inu ẹni to se agbatẹru eto ẹdawo naa ni eyi jẹ, eto adani rẹ si ni pẹlu, tori, Atiku ko mọ nipa rẹ rara."

Atẹ ti wọn fi n beere owo owo Atiku

Oríṣun àwòrán, @InstaKwara

Bakan naa ni Shaibu salaye siwaju si pe, owo to to ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla, eyi tii se miliọnu mẹrindinlogoji naira, ni awọn eeyan ọhun kede pe awọn fẹ kojọ fun Atiku lati fi se ẹjọ to pe lori esi ibo aarẹ, to si jẹ pe ni ọjọ kansoso pere, wọn ti ri owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira.

Àkọlé fídíò, Nigeria Election 2019: Ará Eko pariwo ohun márùn-ún tí wọn ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba tó ń bọ̀

Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti pa ikede ọhun rẹ lori oju opo ikansira ẹni Twitter ti wọn gbe si, sibẹ agbẹnusọ fun oludije ẹgbẹ APC naa wa n kesi awọn araalu lati takete si ẹdawo ọhun nitori kii se eyi ti Abubakar Atiku lọwọ si.