Ekiti: Lẹ́yìn ààwọ òṣèlú, gómìnà Ekiti méjì fẹ̀rín pàdé ara wọn

Oríṣun àwòrán, Twitter/Govt. of Ekiti State
Ta ba gbagbe ọrọ ana, a ko ni rẹni ba sere. Eyi lo mu ki gomina ipinlẹ Ekiti Kayode Fayemi ati gomina ana nipinlẹ naa, Ayo Fayoṣe, di mọ ara wọn nibi ayẹyẹ kan l'Ọjọru.
Fayẹmi to sọ ọrọ apilẹkọ nibi ayẹyẹ idanilọla ni iranti ọjọ ibi Oloye Obafemi Awolọwọ, eyi ti agbẹjọro agba Afẹ Babalọla se agbatẹru rẹ niluu Eko, n pada lọ si ijoko rẹ, nigba ti Fayose dide lati lọ ki, ti awọm mejeeji si so mọ ara wọn.
Bo tilẹ je pe Fayẹmi ti fi ọgbọn sọrọ si Fayoṣe ninu ọrọ apilẹkọ rẹ, ninu eyi to ti sọ pe agbẹjọro Afẹ Babalọla ti da iyi ipinlẹ Ekiti pada, yatọ si awọn kan to jẹ pe ohun amayedẹrun to n mu inu kun nikan ni wọn mọ.
Ṣugbọn Fayoṣe kọ eti ikun si ọrọ naa, o si dide lati ki Fayẹmi nibi ayẹyẹ ọhun.
Awọn eeyan to wa nijoko bu sẹrin, bi Fayẹmi ati Fayoṣe ti na ọwọ ara wọn soke.
Bẹẹ ba gbagbe, Kayọde Fayẹmi lo gbo ewuro soju Kolapọ Olusọla ti ẹgbẹ PDP, ti Ayọdele Fasoye n se atilẹyin fun, ninu ibo gomina ipinlẹ Ekiti, amọ ti Fayoṣe sọ pe eeru ni ẹgbẹ APC fi wọle ibo naa.









