2019 Election Update: Ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ fún Atiku láyè láti ṣàyẹ̀wò ohun èlò ìdìbò ààrẹ

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Facebook/Atiku Ababakar

Àkọlé àwòrán, Ibo aarẹ orilẹede Naijiria

Igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun lori ibo ti fun oludije si ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar lanfani lati ṣayẹwo ohun elo idibo ti ajọ INEC lo lasiko ibo aarẹ ọjọ kẹtalelogun oṣu keji.

Ninu idajọ rẹ, adajọ Abdul Aboki sọ pe Atiku lẹtọ lati ṣayẹwo ohun elo idibo ti ajọ INEC lo gẹgẹ bi ofin to de eto idibo lorilẹede Naijiria ti sọẹ agbekalẹ rẹ.

Ṣugbọn adajọ Aboki ni Atiku ko ni lanfani lati ṣe ẹda awọn ohun idibo naa nitori ofin ko faye gba a.

Àkọlé fídíò, Nigeria Elections 2019:Ìbò la ní kí ẹ dì, àwa kò bá tìjà wá

Awọn meji yoku Peter Ige ati Emmanuel Agim ti wọn wa ninu igbimọ ẹlẹni mẹta naa faramọ idajọ ọhun.

Aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ osẹlu APC ti wọn fẹsun kan ko si nibi igbẹjọ ọhun.

Agbẹjọro agba Livy Ozoukwu lo ṣoju Atiku Abubakar ati ẹgbẹ oṣelu PDP nibi igbẹjọ naa.