Nigeria Elections 2019: Dandan ni lílo ẹ̀rọ tó ń yẹ káàdì ìbò wo

Káàdì ìdìbò alálòpẹ́

Oríṣun àwòrán, INEC NIGERIA/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán, Àjọ elétò kéde ọjọ́ ajé tó mbọ̀ láti gba káàdì ìdìbò
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Laipẹ yii ni Alaga ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu kede pe, dandan ni ki ajọ naa lo ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi oludibo ni gbogbo ibudo idibo ni Naijiria.

O ni eyi yoo mu ki ajọ INEC ṣe eto idibo ti awọn eniyan yoo ni igbagbọ ninu rẹ.

Lilo ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi oludibo fa ede aiyede, lẹyin ti eto idibo aarẹ waye lọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, paapa nitori bi awọn kan ko ṣe lanfaani lati dibo, nitori pe ẹrọ naa ko gba kaadi wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa ni oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar naa sọ pe, ara nkan ti oun fi kọ esi idibo naa ni pe oun ko gbagbọ pe oun fidirẹmi nitori pe, wọn ko lo ẹrọ naa ni awọn agbegbe kan.

Kíní yóò ṣẹlẹ̀ ni ibùdó tí ẹ̀rọ ayẹkaadi ìdìbò wò kó ba ṣiṣẹ́

Ọga agba fun ẹka eto idanilẹkọ fun awọn oludibo lọọfisi ajọ INEC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Amofin Jacob Ayanda salaye fun BBC pe, wọn yoo wọgile esi ibo ni ibudo idibo ti wọn ba ti dibo lai lo ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi oludibo.

Bakan naa lo sọ pe, ẹnikẹni ti ẹrọ naa ko ba gba ika idibo rẹ̀, ṣugbọn to gba kaadi, iru ẹni bẹẹ yoo lanfaani lati dibo, amọ yoo kọ nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ silẹ.

Oludibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sugbọn, ẹni ti ẹrọ naa ko ba gba kaadi, ti ko si tun gba ika, o tumọ si wipe ko si akọsilẹ nipa oludibo ọhun nibudo idibo naa.

Ati wi pe, ofin eto idibo ni Naijiria sọ pe eto idibo yoo waye ni ọjọ keji ọjọ idibo ni ibudo yoowu ti ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi oludibo ko ba ti ṣiṣẹ rara fun gbogbo awọn oludibo to wa nibẹ, titi di aago meji ọsan to yẹ ki idibo pari.