Algeria: Ààrẹ Bouteflika ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdun márun, tó tún fẹ́ dìje padà

Oríṣun àwòrán, AFP
Ni orilẹede Algeria, ó soro láti róye bíi ààrẹ orilẹ̀-ede naa, Abdelaziz Bouteflika to jẹ́ ẹni ọdun mẹ́jìlélọ́gọ́rin, yoo se dari orilẹede naa, nitori pe ó ti ni àìsàn rọ́pa rọsẹ̀ láti bii ọdun mẹ́fà sẹ́yin, ìnira si ní ìrìn àti ọ̀rọ̀ sísọ gan jẹ fun un.
Ó jẹ́ ohun ti ènìyàn kò si lée gbàgbọ́ nígba ti wọn kédé pé Abdelaziz Bouteflika, yoo tun dije fun ìgbà káàrún nínú osu kẹ́rin, Bouteflika ko tilẹ yoju lọjọ àìkú láti wa forukọ silẹ̀ pé òun fẹ dije.
Eyi kún ohun to faa ti onírúru iwa ehonu ṣe bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Algeria, ti àwọn akẹkọ̀ọ́, olùkọ́, agbẹjọrò àti àwọn akọroyin bẹ́rẹ̀ si ni fẹhonu han, ti wọn sì ń wọ́de kiri ìgboro, èyi to n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, wọn kò fẹ́ ki ààrẹ ti kò le pasẹ ó dari àwọn mọ.
Ọ̀pọ̀ araalu ni ọ̀rọ̀ náà ń kọ lóminu pé, ti ko ba si elòmíràn ti wọn lee fi rọ́pò ààrẹ Bouteflika, to ti di ààrẹ láti ọdun 1999, eyi lée da omí ètò ijọba rú, to ba fi kú sórí aleefa.









