BBC Africa Eye: O yẹ kí ìjọba ló ìmọ̀ ẹ̀rọ ìwádìí sátáláìtì láti mú àwọn Boko Haram

Aworan ẹni ti wọn de ọwọ rẹ

Awọn ọmọ Naijiria ti n sọ ero ọkan wọn nipa fidio iwaadi bi awọn agbofinro ṣe n fi iya jẹ awọn afunrasi eleyi ti BBC Africa Eye gbe jade.

Loju opo Facebook ileeṣẹ BBC Yoruba, niṣe ni awọn eeyan bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbofinro wọnyi ko ṣe bọwọ fun ofin.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ki ijọba kasẹ awọn SARS kuro nilẹ lawọn miiran n sọ pe ki BBC ṣe idayatọ awọn afunrasi ati awọn ti ko mọwọ mẹsẹ ninu iwaadi wọn.

Bẹẹ lawọn miran n beere pe kilode ti ijọba ko ṣe le fi iru ẹrọ iwaadi satalaiti ti wọn lo ninu iwaadi yi lati fi mu awọn ikọ Boko Haram.

Showemimo Victor ti o beere ọrọ yi sọ ọ ni ede Gẹẹsi.

Aworan esi oju opo BBC Yoruba

Ninu esi tirẹ, Micheal Alloh naa fẹ ki wọn lo iru imọ yii lati tọ pinpin awọn to jẹ alajẹbanu oloṣelu.

Aworan esi oju opo BBC Yoruba

Ni akotan pupọ awọn to ka nipa iroyin naa loju opo BBC lo kan sara si ileeṣẹ iroyin naa ti wọn si ni awọn ni ireti pe ijọba yoo wa nkan ṣe si ọrọ awọn agbofinro to n fi iya jẹ awọn afunrasi.