Ekiti Maternity Leave: Ìjọba Ekiti ní ìdẹ̀rùn àwọn aráàlú tó jẹ wọ́n lógún ló fa ìsinmi oṣù mẹ́fà fáwọn ìyálamọ

Awọn iyalọmọ to pọn ọmọ sẹyin

Oríṣun àwòrán, Silver Lining NG

Awọn obinrin to jẹ osisẹ ijọba nipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si n gboriyin fun ijọba ipinlẹ naa, lẹyin to kede isinmi oloṣu mẹfa fun awọn obinrin to jẹ oṣiṣẹ ijọba to ba ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun.

Lara awọn eeyan naa to ba BBC sọrọ sọ pe, inu wọn dun pupọ fun igbeṣẹ naa ti ijọba ọhun gbe.

Arabinrin Kemi sọ pe "Igbesẹ yii dara pupọ, o si jẹ eyi ti yoo fun awọn obinrin laaye lati ṣe itọju ọmọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kẹmi ni akoko isinmi naa yoo fun awọn abiyamọ laye lati ṣe itọju to peye fun ara wọn ati fun ikoko to ṣẹṣẹ wa saye.

O tẹ siwaju pe "Isinmi oṣu mẹta ti wọn n fun wa tẹlẹ ko to rara, a kan n fara daa ni."

Kemi tẹsiwaju pe, "awọn obinrin mii ma n fun ọmọ wọn ni ọmu nikan lai fi omi laa, to tumọsi pe, iru obinrin bẹẹ nilo isinmi ọlọjọ gbọrọ ki ara rẹ le padabọ sipo."

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, @GovUzodinma

Ni ti arabinrin Ogbuke, o ni idunnu ati ayọ nla ni iroyin isimi oloṣu mẹfa naa jẹ fun awọn obinrin Ekiti, nitori oṣu mẹta ti kere ju lati ṣe itọju ọmọ tuntun.

Ogbuke sọ pe isimi oloṣu mẹfa naa yoo fun awọn obinrin ni anfani lati fun ọmọ wọn lọmu fun oṣu mẹfa gbako lai si idiwọ iṣẹ.

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, @EKSDGs

Kọmiṣọna fun eto iroyin ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Muyiwa Olumilua sọ pe idi ti Gomina ipinlẹ naa, Kayode Fayemi ṣe gbe igbesẹ ọhun ni lati mu aye dẹrun fun awọn eeyan ipinlẹ Ekiti.

Olumilua sọ fun BBC pe, ṣise afikun si akoko isinmi awọn abiyamọ naa yoo fun wọn lanfani ati sinmi si, ki ara wọn lee mokun daadaa ki wọn to pada sẹnu iṣẹ.

O ni, ṣe ni ijọba Ekiti n tẹle amọran awọn eleto ilera to sọ pe, o yẹ ki iya ọmọ fun ọmọ jojolo lọmu fun oṣu mẹfa, leyi ti yoo nira lati se, ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ.