Cabinet reshuffle: Sajid Javid kọ̀wé fipò Káńsélọ̀ sílẹ̀, Rishi Sunak gba ipò rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan pataki lara awọn adari ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sajid Javid ti kọwe fipo silẹ, lẹyin ti olori ijọba Boris Johnson ṣe atunto igbimọ ijọba orilẹ-ede naa.
Ikọwe fiposilẹ yii lo waye lẹyin ti ilẹ Gẹẹsi yapa kuro lara ajọ Iṣọkan ilẹ Yuroopu.
Ọgbẹni Javid kọ lati fọwọ osi juwe ile fun awọn to n ba ṣeṣẹ ni bo ṣe sọ pe kii ṣe ohun dara lati ṣe.
- Olùdíje gómìnà APC ní Bayelsa ti ń palẹ̀mọ́ fún ìbúra, kílé ẹjọ́ tó ga jùlọ tó yẹgi mọ́ nídìí
- Lẹ́yìn ọdún 44 tó jáde láyé, igbá tí onírèsé Murtala Muhammed fín sílẹ̀, kò parun
- Ẹ̀yin òṣèrè tíátà, ẹ ní ṣùúrù de àsìkò Ọlọ́run, ẹ máṣe kánjú kọjá kádàrá - Madam Ṣajẹ
- "Iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò máa ń mú ẹ̀wà àti àpọ́nlé ba ni àmọ́ kò lówó lórí"
Oṣu keje ọdun 2019 ni Boris Johnson yan Sajid sipo lẹyin to gori alefa gẹgẹ bi olori ijọba ilẹ Gẹẹsi.
Ki Sajid to kọwe fiposilẹ, awọn ahesọ kan ti n waye pe họwuhọwu wa laari rẹ̀ ati ọgbẹni Dominic Cummings, to jẹ olubadamọran pataki si Boris Johnson.
Ni bayii, wọn ti fi Rishi Sunak rọpo rẹ.

Oríṣun àwòrán, @htTweets
Rishi Sunak jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji, o si kawe ni Winchester College ati Fasiti Oxford lẹyin naa lo da ileeṣẹ aladani kan silẹ.
Sunak di minisita fun eto ilegbe lọdun 2018 ko to ri igbega sipo akọwe iṣura orilẹ-ede Gẹẹsi.












