Revolution Now: Adájọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ sí March 11, 12 àti 13

Ileẹjọ tun ti sun igbẹjọ siwaju lori ẹjọ ẹṣun ete lati ditẹgbajọba ti ijọba apapọ pe asaaju ẹgbẹ ajijagbara Revolution Now, Omoyele Sowore.
Lọjọbọ ni igbẹjọ naa bẹrẹ nile ẹjọ giga to wa nilu Abuja eyi ti Adajọ Ijeoma Ojukwu ko sodi, ti adajọ si pasẹ pe ki ijọba apapọ san owo gba ma binu fun Sowore lori bo se n fi ẹjọ naa falẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- Láì lọ́wọ́ ẹ̀yin aráàlú nínú, yóò nira fún Boko Haram láti ṣọṣẹ́ - Buhari sọ fáwọn èèyàn Borno
- Sunday Igboho gba àwọn èèyàn Soka n‘Ibadan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ tó wá ṣọṣẹ́
- Àgbà olórin, Victor Olaiya jáde láyé.
- Jospeh Yobo ti di igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tuntun
- Ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Ondo buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn
- Ẹ wo àwọn ìlérí tí Buhari ṣe láti ọdún 2015 àmọ́ tí kò tíì mú ṣẹ
Nigba to yọju sile ẹjọ loni, Omoyele Sowore ati ẹnikeji rẹ ti wọn dijọ n jẹjọ, Bakare sọ fun ileẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun onikoko meji tijọba apapọ fi kan awọn, ti adajọ̀ si fidi rẹ mulẹ pe, ijọba apapọ ti san owo naa.
Lasiko igbẹjọ naa si ni igun olupẹjọ se atunse si awọn ẹsun to fi kan Sowore eyi to nii se pẹlu didi ọtẹ lati gba ijọba ati iditẹ lati gbajọba.

Bamubamu si lawọn agbofinro pe sile ẹjọ lasiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ, ti wọn ko si fẹ ki agbofinro ya fọto Soworẹ.
Bakan naa si lawọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara Revolution Now peju sile ẹjọ, ti wọn si gbe oniruuru aksle lọwọ eyi ti wọn fi n sọ nipa ohun ti ẹgbẹ wọn duro le lori.
Adajọ Ojukwu ti wa sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kọkanla, ikejila ati ikẹtala osu Kẹta ọdun 2020.









