Adeola Smart and Malivehood Wedding: Diamond kún ara aṣọ ìyàwó, Cake jẹ́ alájá 16

Oríṣun àwòrán, Istagram/malivelihood
Ọpọ eeyan to peju sibi igbeyawo Adeola Smart, tii se ọmọbinrin Senatọ Smart Adeyemi ati ọkọ rẹ, Olusola Awujoola ni ko ni gbagbe aramọnda igbeyawo naa laelae.
Idi ni pe awọn isẹlẹ manigbagbe lo waye nibi igbeyawo naa, ti ko fẹ sẹlẹ ri lorilẹede Naijiria.
Ọjọ manigbagbe si ni ọjọ Satide, ọjọ Karun osu Kejila ọdun 2020 naa ti eto igbeyawo ọhun, ti wọn pe ni igbeyawo ọmọ ọba waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìlú méjì kọjú ìjà síra wọn l‘Ondo torí aáwọ̀ ilẹ̀, ọba kan wà ní ‘Coma’, èkejì fo ògiri jáde
- Ọmọ Naijiria hú ẹ̀sùn ìfipá bánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan Fatoyinbo síta lẹ́yìn tó lọ sí Shiloh
- Ìdí rèé tí mo fi yan ikọ̀ PMS rọ́pò NURTW nípìnlẹ̀ Oyo - Seyi Makinde
- Ìwọ́de ńlá yóò bẹ́rẹ̀ lọ́jọ́ táwọn gómìnà bá yá ₦17trn nínú owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́ - NLC
- "Buhari, Olóṣèlú àtàwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ló mú àjẹbánu gogò ní Nàíjíríà"
- Ooni Adeyeye ti Ile Ife fẹ sèrànwọ́ owó iléèwè fún akẹ́kọ̀ọ́ 5 mílíọ̀nù ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọn he lẹ́yìn tó lu obìnrin ní jìbitì ìfẹ́ tí iye rẹ̀ tó $15,000 lórí ayélujára
- Fr Mbaka, ọmọ ìjọ rẹ̀ kọ̀lu akọ̀ròyìn BBC, wọ́n lù wọ́n ní àlùdojúbolẹ̀
- Háà! Àgbo tí mò ń lò láti jò kó bá mi, ìdí mi ti yọ́ tán - Nkechi Blessing figbe ta
Iyatọ nla si lo wa nipa igbeyawo naa si eyi to ti n waye tẹlẹ, bẹrẹ lati ori ife imumi, akara oyinbo, ẹbun wi wọn ha, ounjẹ ti wọn se ati asọ iyawo funra rẹ.
Awọn eeyan to lorukọ yika Naijiria si ni wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ igbeyawo naa, eyi to kasiara.
Awọn ohun aramọnda to mu ki igbeyawo naa yatọ ree:
Akara Oyinbo:

Oríṣun àwòrán, Instagram/cakes_by_la
- Miliọnu mẹrin naira ni wọn fi se akara oyinbo naa gẹgẹ bi wọn se ni iyawo funra rẹ kede
- Osu mẹrin ni wọn fi gbaradi fun sise akara oyinbo naa
- Awọn onimọ nipa akara oyinbo mejidinlogun lo se akara oyinbo naa fun ọjọ marunlelaadọfa gbako
- Ile nla bii aafin ọba ni wọn fi akara oyinbo igbeyawo naa se
- O ga ni iwọn bata mejidinlaadọta
- Aja mẹrindinlogoji lo ni
- Iwọn ọgọsan kilogiramu suga ni wọn fi se akara oyinbo naa
- Ẹgbẹlẹgbẹ awọn ododo to jẹ kiki suga si lo wa lara rẹ.
Asọ igbeyawo ti iyawo wọ:

Oríṣun àwòrán, Instagram/thebridalmoments
Kaba iyawo ti arabinrin iyawo asẹsẹgbe naa wọ lọ sile ijọsin lo kun fun kiki okuta olowo iyebiye diamond.
Orukọ iya iyawo to ti di oloogbe, tii se Yemisi, ni wọn kọ si ara asọ iboju ti wọn ran si ara asọ igbeyawo naa, eyi ti wọn fi diamond kọ.
Ẹjẹ Igbeyawo:

Oríṣun àwòrán, Istagram/malivelihood
Nigba ti wọn wa nile ijọsin, bo se wu ọkọ iyawo lo sọ ẹjẹ igbeyawo rẹ, ti ko si tẹle ilana ẹjẹ ti ile ijọsin maa n ka fun tọkọtaya.
Ọkọ iyawo naa, ti ọpọ eeyan mọ si Malivelihood lo jẹ ilumọọka onisowo okuta iyebiye bii goolu, diamond ati awọn ẹsọ ara lorisirisi.
Nigba to yẹ ko sọ pe ni '...Ni didun ati nigba ikoro, nigba ilọrọ ati nigba ipọnju...' amọ se ni Malivehood sọ pe ',,,Nigba ilọrọ ati nigba Ilọrọ.
Bẹẹ si ni iyawo rẹ, Adeola naa n dinju si, to si n na ika soke pe o kare lae fun bo se sọ ẹjẹ rẹ ọhun.
Ẹbun ti wọn pin nibi igbeyawo:

Oríṣun àwòrán, MojiDelano
Ohun to tun jẹ ara meeriri ta gbọ nipa igbeyawo naa ni bi awakọ kabukabu kan, ti orukọ rẹ n jẹ Austin to gbe alejo lọ sibi ayẹyẹ naa, se jẹ ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kan ti wọn fi dije nibẹ.
Iye owo ayọkẹlẹ Lexus naa ni miliọ̀nu mẹ́ta ati ẹgbẹrun lọna irinwo naira (N3.4m).
Bakan naa ni awọn alejo miran tun jẹ ẹbun aago ọwọ olowo iyebiye, eyi ti wọn fi se ẹbun hiha nibi igbeyawo naa.
Sise ibudo ayẹyẹ ni ọṣọ - Decoration:

Oríṣun àwòrán, Istagram/malivelihood
A gbọ pe ẹgbẹrun meji apo ododo ni ọkọ nla mẹfa wa ja sibi ayẹyẹ naa, eyi ti wọn lo lati fi se ibudo igbalejo fun ayẹyẹ igbeyawo ọhun ni ọṣọ to rẹwa.















