Nkechi Blessing: Àgbo tí yóò mú mi tíírín ti jẹ́ kí ìbàdí mi lọ sílẹ̀

nkechi blessing sunday

Oríṣun àwòrán, nkechiblessingsunday

Pupọ ninu awọn eeyan to sanra lo maa n wa ọna lati jo, yala nitori ilera ara wọn tabi nitori oju ti awọn eeyan fi n wo wọn lawujọ.

Ẹwẹ, lọpọ igba ti awọn miran ba bẹrẹ si n lo awọn oogun tabi agbo to le mu ki wọn jo, ni wọn ki n fẹran bi wọn ṣe maa n ri mọ, nitori wọn maa n jo ju bi wọn ṣe fẹ lọ.

Eyi lo difa fun gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Nkechi Blessing, to ke gbajare loju opo Instagram rẹ pe oun ko fẹran bi oun ṣe ri, lẹyin ti oun bẹrẹ si lo agbo kan lati dena ara sisan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ṣe sọ, oun n lo agbo ọhun koun ma baa sanra ju, ṣugbọn o dabi pe oṣere naa ko fẹran bo ṣe ri mọ.

O ni "mi o ṣe mọ o! Ko yẹ ki n le sare jo bayii laarin ọjọ perete."

Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, nkechiblessingsunday/Instagram

Nkecho sọ pe, ọpọ awọn ololufẹ oun lo ti bẹrẹ si n beere pe ki ni ohun to ṣẹlẹ, ti oun fi n dinku lojojumọ.

O sọ siwaju sii pe, oun yoo dẹkun ati maa lo agbo naa ki oun to poora nitori bi oun ṣe n yọ jo naa ko tẹ oun lọrun.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ kan to fi ọrọ naa lede lo tun sọ loju Instagram kan naa pe, agbo ọhun ti n jẹ ki adinku de ba ibadi oun.

nkechi blessing sunday

Oríṣun àwòrán, nkechiblessingsunday

O ni "lẹyin ti mo wo inu digi daadaa lonii, mo ṣakiyesi pe ibadi mi ti n lọ silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Nkechi sọ ṣaaju pe oun ko fẹran bi oun ṣe n yọ jo, o ni oun fẹran bi ibadi oun ṣe ri lasiko yii nitori ẹru nla ni ibadi naa jẹ fun ẹsẹ oun lati maa gbe.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú