Muhammadu Buhari: Amòfin Adebayo wá kábàámọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń tọwọ́ òṣèlú bọ

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Oni Ọjọbọ lo yẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari farahan niwaju ijoko ile asofin apapọ fun ilẹ Naijiria.
Ọsẹ to kọja ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin ranṣẹ si, nitori ọrọ eto aabo aabo to mẹhẹ yika Naijiria.
Igbesẹ awọn asofin lati ransẹ pe Buhari waye lẹyin ti ikọ Boko Haram pa awọn agbẹ kan nipinlẹ Borno.
Ariyanjiyan si ti n waye lori boya Buhari yoo lọ ọ tabi ko ni i lọ, paapa lẹyin ti Agbẹjọro Agba Naijiria, to tun jẹ Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami sọ l'Ọjọru pe, awọn aṣofin ko ni ẹtọ labẹ ofin lati ranṣẹ pe Buhari.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obasanjo àti Gani Adams tẹ́ mi pẹ̀lú bí wọn ṣe tahùn síra wọn - Adebanjo
- Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò takú láti gba èsì ìbò ààrẹ ní Ghana
- Ọ̀pọ̀ nkan tó n ṣẹlẹ̀ kò jẹ́ kí n gbàgbọ́ pé Naijiria wà ní abẹ́ ìdarí ẹnikẹ́ni - Wole Soyinka
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣoro ní Ijebu Ode, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo fi lọ sílé Tinubu - Rashidi Ladoja
- ‘Sim Card’ títà àti ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀ dèèwọ̀ ní Nàíjíríà - NCC
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
Awijare Malami ni pe aarẹ ti ṣe aṣeyọri to pọ, "fun bo ṣe da yinyin ado oloro, ipaniyan, ati biba dukia jẹ duro", ko to o di aarẹ lọdun 2015.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
O ni awọn ilana ti Buhari n gba yanju ọrọ eto aabo gẹgẹ bi Oludari gbogbo ileeṣẹ aabo, kii ṣe nkan ti gbogbo aye gbọdọ mọ.
Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro kan, Amofin Sali Adebayo sọ fun BBC Yoruba pe "awọn ofin fi aaye gba awọn aṣofin, lati ranṣẹ pe aarẹ lori ohunkohun ti wọn ba n fẹ alaye lori rẹ".
Amofin Adebayọsọ pe wọn ni agbara lati yọ ọ ni ipo aarẹ, to ba kuna lati farahan niwaju wọn, pẹlu ibo ìdá meji ninu mẹta apapọ wọn.
"Iyẹn ti wọn ko ba ṣe ojusaaju oṣelu nitori o ṣe ni laanu pe ọpọ nkan ni a n fi ọrọ oṣelu yanju ni Naijiria.
"O si ṣe e ṣe ki awọn aṣofin ma ṣe nkankan fun Buhari ti ko ba yọju si wọn, nitori pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC, lo pọju nibẹ.
"Wọn ko si ni i ṣe ohunkohun lati tako ẹgbẹ wọn."
Ilé aṣòfin kò láṣẹ kankan láti pe ààrẹ Buhari wá rojọ́ lórí ọ̀rọ̀ ètò àbò - Malami

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency Nigeria
Saaju la ti sọ fun yin pe, Agbẹjọro agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami ti ni ile igbimọ aṣofin ko lẹtọ labẹ ofin lati pe aarẹ Muhammadu Buhari wa siwaju wọn lati wa ṣalaye ohunkohun.Malami ṣipaya eyi l'Ọjọru ọsẹ ninu ọrọ to pe akọle rẹ ni "Pipe Buhari lẹjọ: Ile aṣofin n ṣe lodi alakalẹ ofin".Agbẹjọro agba ni "ile igbimọ aṣofin ko lagbara kankan labẹ ofin lati gbero rẹ tabi ṣe agbekalẹ eto ti o le pe aarẹ ko wa ṣalaye ọrọ lorii iṣẹ awọn ologun ati bi wọn ṣe n lo wọn.
- Èyí ni àwọn aṣíwájú ìjọba tí ajé ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí láàrin ọdún 1960 sí àsìkò yí
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria Kolawole
- Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ti wọ Ààfin Ile Ife fún ìgbà àkọ́kọ́
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
Bakan naa, o mẹnu ba pe ẹtọ ti aarẹ ni lati yan pe oun fẹ farahan niwaju ile aṣofin lati ba wọn sọrọ torinaa ki ile aṣofin maa pe aarẹ lẹjọ tabuku ba ipo aarẹ.Ni ọjọ kinni oṣu kejila ọdun ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin da abaa ki wọn pe aarẹ Buhari lati wa jabọ fun wọn lorii otitọ to wa nidii ọrọ abo lorilẹede Naijiria.Wọn ṣe ipinu yii lasiko ijoko ile kan nibi ti ọmọ ile to n ṣoju ipinlẹ Borno sọ aba kan lorii iṣẹlẹ bi Boko Haram ṣe ṣekupa awọn agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji nipinlẹ rẹ.Ẹwẹ, ni idahun si eyi, oluranlọwọ pataki si aarẹ lori ọrọ ori ayelujara, Lauretta Onochie kede lọjọ Aje wipe Aarẹ yoo ba apapọ ile igbimọ aṣofin sọrọ.













