Victoria Kolawole: Òṣèré tíátà Yorùbá ní òun kò tíì ṣe ìgbéyáwó àmọ́ òun kò wá ọkọ''

Osẹre Victoria Kolawole

Oríṣun àwòrán, Instagram/victoriakolawole

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oṣere tiata Yoruba Victoria Kolawole sọrọ o fa komookun rẹ yọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

Victoria ya agbado ha sawọn eeyan lẹnu nigba to fesi si ibeere ti ẹnikan beere pe kilode to maa fi n ṣi ara silẹ.

Idahun rẹ ni pe ara oun rẹwa lo jẹ ki oun maa ṣi ara mi silẹ.

Ti ẹrin ti ọyaya ni Victoria fi ṣalaye pe ti Ọlọrun ba ṣe ore fun eeyan, ko yẹ ki eeyan maa pa a mọ ra.

''Emi nikan ko le maa da ara mi wo ni jare, ẹ maa binu si mi,'' osẹre Victoria lo sọ bẹẹ.

Nigba ti o sọ nipa bi o ṣe bẹrẹ ere ori itage, Victoria ni awọn obi oun ko kọkọ gba pe ki oun ṣe ere ori itage.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Mama mi tiẹ kunlẹ bẹ mi wi pe ki n maa ṣe ere ori itage nitori ''baba mi ko gbọdọ gbọ.''

Victoria ni baba oun fẹ ki oun kawe di dokita tabi agbẹjọro ni.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

''Ṣugbọn nigba ti owo bẹrẹ si ni wọlẹ, niṣe ni wọn gbaruku ti mi,'' Victoria lo sọ bẹẹ.

''Koda ọkunrin ti mo n fẹ tẹlẹ atawọn obi rẹ naa sọ pe ko le fẹ oṣere,'' Victoria lo ṣalaye bẹẹ.

O ni oun ni lati fi ọrẹkunrin naa silẹ nitori ifẹ ti oun ni si ere tiata.

Oṣere Victoria sọ pe oun ti n ṣere fun bi ọdun mẹwaa bayii.

O tun ṣalye pe awọn ti wọn ni ibalopọ lagbo oṣere tiata nitpri ko si ẹni to le fi tipa mu wọn.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

Victoria ni oṣerekunrin ti ka mi mọ inu yara nile itura ri nibi tawọn ti n ṣere, ṣugbọn ọgbọn ni oun fi le e jade.

Bakan naa ni oṣere naa sọ pe oun ko ti lọ sile ọkọ, amọ oun ko wa ọkọ, ''ẹnikan si wa loju ọpọ bayii.''