Borno Zabamari Massare: Àjọ NCC fẹ́ tú ìwé owó àwọn olúpèsè ìtàkùn ìbánisọ̀rọ̀ wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi eto ibanisọrọ lorilẹede Naijiria, National Communications Commission, NCC ti ni ki gbogbo awọn ileeṣẹ to n pese itakun fun ibanisọrọ lori foonu, dawọ tita kaadi ibanisọrọ duro.
Bakan naa lo ni ki wọn tun dẹkun eto iforukọsilẹ fawọn olubara to n ra kaadi pelebe inu foonu lati fi sọrọ duro ni kiakia.
Oludari ẹka ọrọ to kan araalu labẹ ajọ NCC, ọmọwe Ikechukwu Adinde, l'Ọjọbọ ni awọn pa aṣẹ yii ki ajọ naa baa le ṣe ayẹwo iwe owo iye awọn to n ra afẹfẹ ibanisọrọ lọwọ wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo fi lọ sílé Tinubu - Rashidi Ladoja
- Ààrẹ Akufo-Addo la Mahama mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Ghana fún sáà kejì
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Ilé aṣòfin kò láṣẹ kankan láti pe ààrẹ Buhari wá rojọ́ lórí ọ̀rọ̀ ètò àbò - Malami
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrín Ronke Odusanya àti bàbá ọmọ rẹ̀, Jago? Nkan tí a mọ̀ nìyíì
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
O ni o ṣe pataki fun awọn onibara lati maa tẹle alakalẹ ti wọn yoo maa fi sita titi ti ajọ naa yoo fi pari ayẹwo iwe owo naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni bi wọn ba si rii pe ẹnikẹni ninu wọn kuna ti koju osuwọn, ijọba yoo gba iwe aṣẹ iṣiṣẹ lọwọ wọn.
Igbesẹ yii waye lẹyin ọjọ melo kan ti awọn aṣofin n beere pe ki lode ti ikọ Boko Haram atawọn janduku mii n fi ẹrọ ibanisọrọ ṣe iṣẹ aburu ti ijọba ko si ri wọn mu.
Wọn ni bawo ni wọn ṣe n ri kaadi itakun ibanisọrọ ti wọn forukọ wọn silẹ nigba ti wọn ra a lo ṣugbọn ti o nira fun awọn oṣiṣẹ alaabo lati fi ọwọ ofin mu wọn.
Awọn aṣofin n beere ibeere yii nitori iṣoro aabo to wa lorilẹede Naijiria, paapaa eyi to ṣẹ ṣẹlẹ ti awọn Boko Haram dumbu awọn agbẹ ni ipinlẹ Borno.
Agbẹnusọ ajọ naa tun ni minisita eto ibanisọrọ ati ọrọ aje igbalode, Ọmọwe Isa Pantami lo fun awọn laṣẹ ṣiṣe ayẹwo iwe owo naa ni kiakia.
O ni igbesẹ yii yoo ran awọn to n ta itakun ibanisọrọ yii lọwọ lati maa tẹlẹ ilana to duro ṣinṣin atipe igbesẹ yii ṣe pataki tori ọna ti wọn n gba ṣe iforukọsilẹ awọn to n ra kaadi ọhun ti wọn si fi n ṣiṣẹ ibi.
Èyí ni ìtàn Ọkùnrin tó rí ẹ̀wọ̀n he nítorí àkùkọ aládúgbò rẹ̀ tó pa

Oríṣun àwòrán, @others
Èyí ni ìtàn Ọkùnrin tó rí ẹ̀wọ̀n he nítorí àkùkọ aládúgbò rẹ̀ tó pa
Arakunrin kan lorilẹede France yo lọ ṣe ẹwọn oṣu marun un lori ẹsun pe o yinbọn pa akukọ kan to ni o n pariwo di oun leti.
Akukọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Marcel lagbegbe Ardeche, ni arakunrin naa yinbọn pa nitoeipe o n fi ariwo dii lọwọ.
Lẹyin ti Marcel, iyẹn Akukọ ti a n wi naa ku ni olowo rẹ torukọ rẹ n jẹ Sebastian Verney bẹrẹ si nii kọ iwe ifisun fun idajọ ododo fun un.
Nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan lo ti buwọlu iwe ifisun naa
Ileẹjọ da ọkunrin naa lẹbi lori pe o hu iwa ika si ẹranko at'awọnẹsun miran bẹẹ.
Amọṣa, ileẹjọ ni arakunrin naa ko ni ṣe ẹwọn naa bayii ayafi to ba tun daran miran lọjọ iwaju.
- Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC jáwe lọ gbéle rẹ fún ìgbákejì alága: Hilliard Eta!
- Lóòtọ́ ni ọkọ mi lù mí bí àṣọ òfì, àmọ́ gómìnà ti bá wa parí ẹ̀, ẹ máa gbàdúrà fún ìdílé mi- Dokita Ifeyinwa
- Mi ò kí n ṣe afẹfẹ-yẹ̀yẹ̀ lórí ayélujára nítorí pé mí ò ní dúkìá tí mó le fihàn- Ronke Oshodi-Oke
- Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sì ní gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ìdènà àrùn Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Bakan naa ni wọn tun ni ko san ọọdunrun owo Euro, lẹyin naa ni wọn tun fofin de e pe ko gbọdọ gbe ibọn fun ọdun mẹta gbako.
Arakunrin Verney to ni akukọ naa ni eyi ko lee di ofo to ṣe oun.
O ṣalaye ninu iwe ifisun to kọ pe ajalu nla gbaa lo ṣẹlẹ si ẹbi oun o wa fi kun un pe ki wọn sọ ileto oun di ibudo ikonkan iṣẹmbaye si.
Lọdun to kọja, lorilẹede France yii kan naa ni ileẹjọ ti gbe idajọ kalẹ lẹyin t'awonaladugbo pariwo pe akukọ kan n fi kikọ rẹ di awọn lọwọ lowurọ kutukutu.
- Ìdí rèé táwọn àkàndá ẹ̀dá fi dí iwájú iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pa l'Agodi n'Ibadan
- Ọlọ́pàá, sójà yabo Lekki Toll Plaza láti dènà ìfẹ̀hónúhàn míràn
- Lóòtọ́ ni ọkọ mi lù mí bí àṣọ òfì, àmọ́ gómìnà ti bá wa parí ẹ̀, ẹ máa gbàdúrà fún ìdílé mi- Dokita Ifeyinwa
- Mi ò kí n ṣe afẹfẹ-yẹ̀yẹ̀ lórí ayélujára nítorí pé mí ò ní dúkìá tí mó le fihàn- Ronke Oshodi-Oke
- Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sì ní gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ìdènà àrùn Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì



















