Ghana election: Ààrẹ Akufo-Addo la Mahama mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Ghana fún sáà kejì

Nana Akufo-Ado

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nana Akufo-Ado

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ orilẹde Ghana, Nana Akufo-Addo ti wọlẹ ibo aarẹ ilẹ fun saa keji.

Ọga ajọ eleto idibo ilẹ Ghana, Jean Mensa lo kede pe Akufo-Addo la alatako rẹ, John Mahama mọlẹ ninu eto idibo naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọjọ Aje ni eto idibo naa tawọn ọmọ orilẹede Ghana ti tu yaya tu yaya jade dibo waye.

Ta ni Nana Akufo- Addo to wọle ibo aarẹ Ghana lẹẹkeji?

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1944 ni wọn bi Akufo-Addo ni Accra tii ṣe olu ilu orilẹede Ghana.

Ọgbẹni Akufo-Addo kii ṣe aimọ fuloko lagbo oṣelu orilẹede Ghana.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro agba orilẹede Ghana laarin ọdun 2001 si ọdun 2003.

Nana Akufo Addo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nana Akufo-Addo

Bakan naa ni Akufo-Addo jẹ minisita ọrọ ilẹ okeere laarin ọdun 2003 si 2007 labẹ aṣẹ Aarẹ John Kuffour.

Oun si ni alaga ajọ ECOWAS to n ri si ọrọ aje awọn orilẹede to wa ni iwọ oorun ilẹ Afirika bayii.

Afo-Addo ti kọkọ dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NPP lọdun 2008 ati 2012 ṣugbọn o fidi rẹmi lẹẹ mejeeji.

Lọjọ kẹsan an oṣu kejila ọdun 2016 ni Akufo-Addo tun gbegba ibo aarẹ ninu eyi to ti fẹyin aarẹ Johna Mahama to wa lori oye gbalẹ ti o si wọle.

Mahama naa lo tun fidi rẹmi bayii lẹyin nti Akufo-Addo wọle fun saa keji.