LASU Murder: Àwọn ẹbí ní ìwádìí ọlọ́pàá ṣì ń tẹ̀síwájú ni wọn kò ṣe rí òkú gbà

Favour Daley-Oladele, ti iya, ọmọ pẹlu Pasitọ sekupa lati fi se oogun owo

Oríṣun àwòrán, @femiadi

Eto isinku Favour Daley-Oladele, ti iya, ọmọ pẹlu Pasitọ sekupa lati fi se oogun owo, to yẹ ko waye lọsan ọjọ Isẹgun, ni wọn ti sun siwaju.

Gẹgẹ bi akọroyin BBC to wa nibi isẹlẹ naa ti salaye, ọpọ ero ti pejọ fun isinku naa nitẹ oku Atan to wa ladugbo Yaba nilu Eko, ki iroyin to de pe eto isinku naa ko ni lee waye mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi a ti gbọ lati ẹnu awọn ẹbi oloogbe to ti de sitẹ oku naa, awọn alasẹ ileesẹ eto ilera nipinlẹ Eko lo pasẹ pe kawọn ẹbi naa ma ti gba oku akẹkọbinrin naa lọ sin.

Awọn eeyan to peju lati sin Favour Daley-Oladele, ti wọn fi se oogun owo

"Awọn osisẹ ileesẹ eto ilera sọ fun wa pe ijọba pẹlu ileesẹ ọlọpa fẹ tanna wadi isẹlẹ naa siwaju ki wọn to fun awa ẹbi lasẹ lati lọ sin oku ọmọ wa pada. Koda, a ti fi ọwọ si gbogbo iwe to yẹ lati gba oku naa sita fun sinsin, ki wọn tun to sọ fun wa pe asẹ kan to wa lati oke ni wọn ko gbọdọ gbe oku naa fun wa."

Awọn akẹẹgbẹ Favour Daley-Oladele ti wọn peju lati sin oku rẹ

Awọn eeyan to peju sibi eto isinku naa, ti iroyin ọhun ba lojiji, si ti n pada lọ sile lọọkọkan.

Isinku akẹkọọbinrin LASU ti wọn fi se oogun owo bẹrẹ l‘Eko

Awọn akẹẹgbẹ Favour Daley-Oladele ti wọn fi se oogun owo

Laipẹ yii la mu iroyin wa fun yin pe, awọn ẹbi, ọrẹ ati akẹẹgbẹ akẹkọbinrin ileeẹkọ fasiti Eko, LASU, Favour Daley-Oladele, ti iya ati ọmọ kan fi se ọbẹ alata fun oogun owo laipẹ yii, ni wọn ti n de si itẹ oku Atan ladugbo Yaba, nilu Eko.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi eto isinku naa jabọ pe se ni oju awọn eeyan naa, to peju sibi eto isinku yii faro, ti wọn si n kẹdun iku ojiji to mu arabinrin naa lọ.

Bẹẹ ba gbagbe, Pasito ijọ alaṣọ funfun kan, Segun Philip ati Adeeko Owolabi to jẹ ọrẹkunrin Favour pẹlu iya rẹ, Bola Oladele ni akara tu sepo pe wọn fi ọmọbinrin naa se oogun owo.

Awọn akẹẹgbẹ Favour Daley-Oladele ti wọn fi se oogun owo

Pasitọ Philip ati Owolabi jẹwọ pe lootọ lawọn pa Favour lati fi ṣe oogun owo, amọ ẹlẹda ọmọbinrin naa ko jẹ ni ni oogun owo.

Itẹ oku Atan nilu Eko

Lọwọlọwọ bayii, Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun ti hu oku akẹkọọbinrin fasiti ipinlẹ Eko LASU, ti awọn afurasi naa si ti wa ni gbaga ile iṣẹ ọlọpaa lori ẹsun pe wọn jọ gbimọ pọ pa ọmọbinrin naa ni

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

Bi eto isinku naa ba se n lọ, la maa mu wa fun yin.