Oluwo: Oluwo fárígá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àgbékalẹ̀ iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni

Kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1

Àkọlé àwòrán, Oluwo fárígá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àgbékalẹ̀ iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni

Kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti kebosi sita pe bi ijọba apapọ ko ba gbe ileẹkọ olukọni onipo kinni to fẹ da silẹ ni ipinlẹ Ọṣun si ilu Iwo, nnkan yoo yan.

O ni pe iwa ọdalẹ leyi yoo jẹ fun atilẹyin ribiribi ti awọn eeyan ilu Iwo ṣe fun ijọba ẹgbẹ Oṣelu APC.

Ọba Akanbi ni ti ileewe giga naa ba ja mọ ilu miran lọwọ nipinlẹ Ọṣun, a jẹ wi pe oun yoo darapọ mọ awọn alatako ijọba apapọ lorilẹ-ede Naijiria ni.

Oluwo ṣalaye pe lara awọn Ọbalaye to duro ti Aarẹ Buhari ni gbangba lasiko ipenija rẹ, ọkan gboogi loun jẹ ninu eyi ti oun ti ṣeto awọn ipade adura itagbangba lorukọ aarẹ ki ilera rẹ lee tubọ gbe ẹnu soke.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'

Oluwo tun sọ ọ laifọtape wi pe ni ojumọ to mọ loni yii, oun loun lee dari omi atilẹyin oṣelu awọn eeyan ilu Iwo si ibi to ba wu oun.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

O wa rọ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu; Igbakeji Aarẹ Yẹmi Oṣinbajo, Oloye Bisi Akande, Rauf Arẹgbẹṣọla pẹlu Gomina Gboyega Oyetọla lati rii daju pe wọn gbe ileewe naa kalẹ si ilu Iwo.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe