2023 presidency: Ààrẹ Buhari ní òun kò leè dá sí ètò yíyan ààrẹ tuntun lọ́dún 2023

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari ní òun kò leè dá sí ètò yíyan ààrẹ tuntun lọ́dún 2023

Ileeṣẹ aarẹ lorilẹ-ede Naijiria ti sọ wi pe Aarẹ Mohammadu Buhari mọ ohun ti yoo ṣe lori ẹni ti yoo joko sori aga aarẹ lẹyin to ba fi ipo silẹ ṣugbọn ko ni fi tipatipa yan eeyan kan lori Naijiria.

Agbẹnusọ fun aarẹ, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina ṣalaye pe ohun ti aarẹ gbagbọ ni pe ẹni to ba wu araalu ni ko wọle kii ṣe lati yan eeyan le awọn ọmọ Naijiria lọwọ.

O ni aarẹ Buhari lee ni ero to ga lori irufẹ eeyan to fẹ ko rọpo oun lati tẹsiwaju pẹlu awọn iṣẹ rẹ gbogbo ṣugbọn oun kọ ni yoo yan le araalu lọwọ.

Ọrọ yii jẹ bii esi si ọrọ kan ti pasitọ agba ni ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare sọ ninu ọrọ akọsọ rẹ fun ọdun 2020 lọjọ Ẹti Wo àwọn ọ̀tá tó ń da orílẹ̀èdè Nàìjíríà láàmú pe Aarẹ Buhari ko gbọdọ kawọ gbera tabi kọ iha kokan mi si igbesẹ ati yan aarẹ ti yoo rọpo rẹ bi o ba kuro lori ipo.

Àkọlé fídíò, Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Fẹmi Adeṣina ni aarẹ ko nilo ẹnikẹni lati ran an leti pe loṣu karun un, ọdun 2023 ni yoo fi ipo silẹ.

Lootọ gẹgẹ bi Pasitọ Bakare ṣe sọ aarẹ fẹ mọ irufẹ ẹni ti yoo gba ipo lọwọ oun ṣugbọn ko ni tọwọ bọ omi igbesẹ ati yan onitọun.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

Bakan naa lo ṣalaye pe Aarẹ Buhari yoo rii daju pe ẹni to ba gun ori itẹ aarẹ lẹyin oun tẹle ilana ti oun fi silẹ, ati pe o mọ le ipinlẹ to ti gbe kalẹ.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe