Asset declaration: Àjọ SERAP ń fẹ́ kí Buhari, Osinbajo, àtàwọn gómìnà kéde dúkìá wọn kọ́jọ́ méje tó pé

Aarẹ Buhari atawọn gomina ipinlẹ kan

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Ajọ ajafẹtọ kan to n fọnrere igbogun ti iwa ijẹkujẹ, SERAP ti fun Aarẹ Buhari, Igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo atawọn gomina pẹlu igbakeji wọn ni gbendeke ọjọ meje lati kede dukia wọn fun araye gbọ.

Ajọ SERAP ni awọn fẹ ki aarẹ ati gbogbo awọn gomina to fi mọ igbakeji wọn o kede iye dukia ti wọn ni, iye owo to n wọle fun wọn lẹkunrẹrẹ gẹgẹ bi wọn ṣe kọọ sinu fọọmu ikede dukia ẹni ti ajọ Code of Conduct Bureau.

Ajọ naa ni kikede dukia awọn to di ipo iṣejọba mu gẹgẹ bi wọn ṣe kọọ silẹ ninu fọọmu dukia ti wọn tọwọ bọ ṣe pataki.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Wọn ni bi wọn ṣe sọ nigba ti wọn fẹ gba ipo naa jẹ eyi ti yoo ran ilu lọwọ lati ṣi aṣọ loju awọn iwa kotọ to ba n waye lori iye dukia tawọn eeyan naa n kede.

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Lara awọn dukia ti SERAP n fẹ ki aarẹ atawọn ẹmẹwaa rẹ to dipo ijọba mu ni apapọ ati ipinlẹ o kede ni owo wọn atawọn dukia bi ile, ilẹ ohun ini miran pẹlu ipin idokoowo lawọn ileeṣẹ aladani ati ti ajọni gbogbo.

Aarẹ Buhari atawọn gomina ipinlẹ kan

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Ajọ SERAP gbe gbedeke naa kalẹ labẹ ẹtọ ofin ọranyan niroyin faraalu, FOI eleyi to ni o kan aarẹ, igbakeji rẹ ati awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji ati igbakeji wọn.

Ajọ naa ni ibeere wọn ọhun labẹ ofin FOI ko tako ẹtọ wọn si aṣiri igbe aye wọn nitorina, gbede ọjọ meje ni wọn nilo lati ṣe ikede naa.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'