Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aworan bi ọja Akẹsan ṣẹ jọna ni Ọjọ Karun un, Oṣu Kini ọdun 2020

Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ọpọ dukia lo ti ṣofo ti ọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan si padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ ina to jo ni ọja Akesan nilu Oyo.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, mọjumọ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ karun un, oṣu kini ọdun 2020 ni iṣẹlẹ yi waye.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, SP Fadeyi Olugbenga sọ pe nnkan bi aago meji oru ni ina naa bẹrẹ.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, O ṣalaye pe kete ti awọn ọlọpaa gbọ iro nkan to n ṣẹlẹ ni ọga ọlọpaa lagbegbe naa atawọn ọlọpaa ti lọ sibẹ.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Olugbenga sọ bakan naa pe awọn agbofinro gbiyanju lati gbogun ti awọn to le fẹ ji nkan gbe nibi iṣẹlẹ naa.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Bo tilẹ jẹ wi pe Olugbenga ni awọn eeyan kan duro lati doju ija kọ awọn panapana ti wọn ni wọn ko tete de lati pa ina naa.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa ni ko si ootọ ninu iroyin pe awọn ọlọpaa yinbon pa eeyan nibi iṣẹlẹ naa.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ wi pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori ina to jo ni Ọja Akẹsan ni ilu Oyo.
Oyo Fire

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Oyo naa wa rọ awọn eniyan lati ṣe pẹlẹ nitori iwadii ti bẹrẹ ni ẹkun rẹrẹ lori ohun to fa iṣẹlẹ naa.

ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí iná tó jó ọjà Akesan - Seyi Makinde

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ wi pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori ina to jo ni Ọja Akẹsan ni ilu Oyo.

Gomina Makinde lo sọ ọrọ yii ni oju opo ikansiraẹni Facebook rẹ lati kẹdun pẹlu awọn to sọ dukia ati ohun ini wọn nu ninu iṣẹlẹ ina to jo naa.

Oyo

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ipenija ina ni ìpínlẹ̀ Oyo lẹnu ọjọ mẹta yi jẹ eleyi to n kan awọn ara ilu lominu.

Ninu ọrọ rẹ, o ni inu oun bajẹ gidigidi bi oun ṣe gbo iroyin naa, ti o si rọ awọn ti wọn sọ ohun ini wọn nu lati ṣe kan akin lasiko yii.

Gomina ipinlẹ Oyo naa wa rọ awọn eniyan lati ṣe pẹlẹ nitori iwadii ti bẹrẹ ni ẹkun rẹrẹ lori ohun to fa iṣẹlẹ naa.

Ọpọ dukia lo ti ṣofo ninu ijamba ina to sọ ni afẹmọjumọ Ọjọ Aiku, Ọjọ Karun un, Oṣu Kini ọdun 2020 ti iṣẹlẹ naa waye.Ẹ wo àwòrán bí ọjà Akẹsan ṣe jóná ràùràù ní ìlú Oyo!

A kò yìnbon pa èèyàn kankan níbi iná tó jó ọjà Akesan ní Oyo- Ọlọ́pàá

Ọpọ dukia lo ti ṣofo ti ọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan si padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ ina to jo ni ọja Akesan nilu Oyo.

Mojumọ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ karun un, oṣu kini ọdun 2020 ni iṣẹlẹ yi waye.

Aworan ina to n jo ni Nairobi Kenya ti a fiṣe afihan ina to n jo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Nigba ti o n fi idi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ BBC, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, SP Fadeyi Olugbenga sọ pe ni nkan bi aago meji oru ni ina naa bẹrẹ.

O ṣalaye pe kete ti awọn gbọ iro nkan to n ṣẹlẹ ni ọga ọlọpaa lagbegbe naa tawọn lọ sibẹ.

O ni: Ni iroyin to tẹmi lọwọ kẹyin, ina naa ti lọ silẹ ṣugbọn wọn ko ti ribi pana rẹ patapata.

Ogbẹni Olugbenga sọ bakan naa pe awọn agbofinro gbiyanju lati gbogun ti awọn to le fẹ ji nkan gbe nibi iṣẹlẹ naa.

Bo tilẹ jẹ wi pe Olugbenga ni awọn eeyan kan duro lati doju ija kọ awọn panapana ti wọn ni wọn ko tete de lati pa ina naa.

Ṣugbọn awọn agbofinro ti pana ifẹhonuhan naa.

Mo fẹ fi to yin leti pe ko si ootọ ninu iroyin pe awọn ọlọpaa yinbon pa eeyan nibi iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Ọga ọlọpaa ṣalaye pe:

Nkan to ṣẹlẹ ni pe awọn ọdọ kan n dana sun taya nitori pe awọn panapana ko tete de.

Awọn wọnyi ati awọn to fẹ yabo agọ ọlọpa la kọdi si, ti ko gba laaye. A ko yinbọn mọ ẹnikankan''

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ boya ẹnikankan ku ninu iṣẹlẹ naa, o sọ pe awọn naa gbọ iroyin pe ọta ibọn ba ọmọkunrin ọdun mẹrinla kan ṣugbọn kii ṣe ọlọpaa lo yinbọn lu u.

O ni awọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu iwadii.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Lẹnu ọjọ mẹta yii, ọwọja ina ni ipinlẹ Ọyọ fẹ peleke ti o si ṣe afihan pe ipenija yi fẹ kọja ipa ileeṣẹ panapana.

Ipenija yi jẹ nkan ti Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde naa mẹnuba loju opo Twitter rẹ pe:

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti rí kí èèyàn ní àwọ̀ ara tó ń ṣí bíi ìpẹ́pẹ́ ẹja rí?

Àwọn aworan yii wa lati ọwọ Google, Facebook ati Twitter