Pásítọ̀ Bakare kéde orúkọ àwọn ọ̀tá tó ń da Nàìjíríà láàmú

Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Tunde Bakare/twitter

Pasitọ ijọ Latter Rain Assembly to tun ti figba kan ri du ipo igbakeji aarẹ lorilẹ-ede Naijiria, Tunde Bakare ti pariwo sita pe ọta mọkanla ni orilẹ-ede Naijiria ni.

Ninu ọrọ kan to sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ lo ti ṣalaye ọrọ yii.

Pasitọ Bakare ni pẹlu bi ọrọ ṣe ri yii, asiko to fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati dẹkun kikan sara sawọn ọta orilẹ-ede naa bayii.

O ni ijọba pẹlu gbọdọ ṣetan lati doju ija kọ awọn ọta orilẹ-ede Naijiria gangan ki wọn lee gba awọn ọmọ Naijiria lọwọ wọbia awọn amunisin to n jẹ gaba lori wọn.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Eyi ni awọn ọta ti orilẹ-ede Naijiria ni gẹgẹ bi Pasitọ Bakare ṣe sọ ọ.

1.Gbogbo awọn ọta orilẹ-ede Naijiria wa lẹka ijọba gbogbo, ni opopona, ile ati ọja gbogbo atawọn to n ta orilẹ-ede wọn lati ni ọrọ

2.Awọn eeyan to gba lati maa woran nigba ti irawọ orilẹ-ede yii fẹ maa wọmi loju wọn.

3.Awọn ayederu iranṣẹ Ọlọrun to n fi iṣẹ Ọlọrun boju ṣiṣẹ ibi lati yan araalu jẹ.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

4.Gbogbo awọn n kopa ninu jijẹ aṣuwọn orilẹ-ede Naijiria lajẹrun pẹlu awọn ti wọn n ṣe baba rere, baba kẹ fawọn to n ko owo ilu jẹ nitori pe wọn jẹ ọmọ ẹya kan naa tabi ẹsin kan naa.

5.Gbogbo awọn to n gbe ẹru owo ori to wuwo le awọn ọmọ orilẹ-ede yii lori.

6.Awọn ijọba ipinlẹ ti wọn n na owo to yẹ fun eto abo fun ara wọn.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'

7.Gbogbo awọn to n lo irinṣẹ ilu lati fi tipatipa gba awọn to ba tako wọn wọlẹ.

8.Gbogbo awọn to yi irinṣẹ ilu ati ipinlẹ wọn di ogun wọn

9.Gbogbo awọn oloṣelu to n ṣe magomago lati fi ibo gbe ẹni tiwọn sori ipo ki wọn lee ko ọrọ ilu ati ipinlẹ si apo ara wọn.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

10.Gbogbo awọn to n ta ibo wọn ti wọn si tun n da wahala ati rogbodiyan oṣelu silẹ

11.Awọn adajọ to n fi ipo iṣedajọ yan alailagbara jẹ tabi ti wọn sọ iṣedajọ di owo ree idajọ ree.

12.Awọn aṣofin ti wọn n ja orilẹ-ede naijiria lole labẹ iboju iṣẹ idagbasoke ilu ti wọn si n ṣe ofin to n dena ominira araalu ti wọn si n ti ipasẹ bẹẹ da omi alaafia ru.

Pasitọ Bakare wa koro oju si ofin ti awọn aṣofin fẹ ṣe lati de ọrọ lori ayelujara.

Amọṣa ajọ ajafẹtọ kan to n gbogun ti ijẹkujẹ, SERAP ti ni awọn mẹrin kan ni ọta orilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

SERAP ni ni iwoye tiwọn, awọn ọta Naijiria ni

1.Awọn aṣofin to n gọ si abẹ iṣẹ akanṣe idagbasoke ilu lati ja orilẹ-ede Naijiria lole owo gọbọi

2.Awọn adajọ to n da oju ẹjọ ru

3.Awọn gomina to n ji owo eto abo ti wọn si n jẹ gaba lori araalu

4.Awọn to n sọ ipinlẹ wọn di ogun ẹbi wọn

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?