Ẹ̀ṣẹ̀ ni fún ọ láti dá fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nílé láì ní àmójútó - Child Protection Network

Ile to n jona

Oríṣun àwòrán, other

Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin iku awọn ọmọde mẹta to jona mọle nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ gba igboro kan.

Awọn ọmọ mẹtẹẹta ọhun, la gbọ wi pe wọn jona mọle laarin oru lasiko ti iya ati baba wọn ko si nile, to si jẹ pe awọn nikan lo da sun sinu ile.

Iroyin ti a gbọ ni pe awọn ọmọ naa ko raaye sa jade lasiko ti ina naa bẹrẹ nitori pe awọn obi wọn ti ti ilẹkun mọ wọn sinu ile lati ita.

Awọn ọmọ ọhun ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mẹrinla, mẹjọ, ati mẹta kagbako iṣẹlẹ buruku naa ni ile wọn to wa ni adugbo Eyin Grammar, nilu Ibadan.

Akọwe agba nigba kan fun ajọ awọn obinrin musulumi to wa fun itọju awọn ọmọ ti ko l'obi lorilẹede Naijiria, FOMWAN, Alhaja Surura Ayero, sọ fun BBC Yoruba pe ko tọ lati da fi ọmọ ti ko tii pe ọdun mejidinlogun silẹ lai si alamojuto kankan.

Nitori pe ni ti ọjọ ori yii, wọn o ti gbaradi lati mojuto ara wọn.

"Kinni ọmọde le ṣe lati ran ara a rẹ lọwọ lasiko ti iru iṣẹlẹ yii ba waye? To ba tilẹ wa jẹ pe obi ko ni si nile, o yẹ ko wa ẹnikan bi mọlẹbi tabi alabagbele to le fi awọn ọmọ naa ti.

Nigba t'oun naa n sọrọ, igbakeji alaga ajọ to n ja fun ẹtọ awọn ọmọ nipinlẹ Oyo, Alhaja Ogungbenro Hairat Omowumi, sọ pe ko lẹtọ fun obi lati fi ọmọ silẹ lai ni amojuto. O ṣalaye pe nkan to ṣe pataki obi ti ko ba le raaye mojuto ọmọ rẹ lati wa ẹnikan tabi ile itọju ọmọde to le ko wọn lọ.

Alhaja Ogungbenro tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ijiya wa l'abẹ ofin orilẹede Naijiria fun obi to ba fi ọmọ rẹ silẹ lai mojuto o, ti nkan buruku ba ṣẹlẹ si ọmọ naa.

"Obi to ba fi ọmọ silẹ bẹẹ, ijiya wa fun un, nitori pe awọn ọmọde ni ẹtọ si amojuto obi wọn."

"Niru iṣẹlẹ yii, ti ijọba ba ri i pe awọn obi awọn ọmọ naa jẹbi lẹyin iwadii, ijiya nla ni fun wọn."

Àkọlé fídíò, Balogun market fire: Olubadamọran gomina sọrọ lori ina náà

Bi o ṣe le dena ijamba ina lasiko ọyẹ

Ri i daju wi pe o pa gbogbo nkan eelo to n lo ina ninu ile ki o to jade, ki o si pa orisun ti ina ti wọ ara wọn ki ina ma baa sọ lara wọn.

Lilo orisun ina kan fun ọpọlọpọ ohun elo to n lo ina le fa ijamba.

Ma ṣe ko eroja bẹtiro pamọ sinu ile lasiko ọyẹ, ki o si ri i daju pe o ko rọ epo si ẹrọ amuna wa rẹ nigba to n ṣiṣẹ lọwọ.