Alcohol: Ó ṣeésẹ kí àwọn ọkùnrin tó maa n mu àmujù ọtí ó maa lo ìwà ipá pẹ̀lú ìyàwó wọn

Oriṣiriṣi ọti lile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ó ṣeésẹ kí àwọn ọkùnrin tó maa n mu àmujù ọtí ó maa lo ìwà ipá pẹ̀lú ìyàwó wọn

Iwadii kan ti fihan wi pe awọn ọkunrin to maa n mu ọti amuju tabi ọti lile tabi oogun oloro l'oṣeeṣe ko maa lo iwa ipa pẹlu awọn ololufẹ wọn.

Abajade iwadii naa ti wọn fi sita ninu iwe ori ayelujara kan, PLOS-Medicine, tan ina se wadii ọpọlọpọ ẹsun nile iṣẹ ọlọpaa.

Bakan naa ni wọn ṣe ayẹwo ileewosan l'orilẹ-ede Sweden fun ọdun mẹrindinlogun ki wọn to gbe abajade iwadii naa sita.

Awọn oluwadii naa tun ri i pe o ṣeesẹ ki awọn ọkunrin to ni aisan ọpọlọ ati iwa kebe-kebe le maa lu ololufẹ wọn

Sugbọn ti wọn ko to ti awọn to n mu ọti amupara ati oogun oloro.

oti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amupara ọti a maa fa wahala ti ko dara fun eniyan

Ọjọgbọn Fasiti Oxford, Seena Fazel, to lewaju iwadii naa sọ pe aabọ iwadii awọn fihan pe wọn le din iwa ipa ninu igbeyawo ku, ti wọn ba ri itọju to peye kuro ninu amuju ọti ati oogun oloro.

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Iwadii naa ti agbarijọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ lati orilẹ-ede America, Sweden, ati ileewe Kings College, London, tọ pinpin ẹgbẹrun lọna ogoje ọkunrin to maa n mu ọti amupara, ati oogun oloro laarin oṣu Kinni, ọdun 1998 si oṣu Kejila, ọdun 2013.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Awọn akọṣẹmọṣẹ ọhun tun ṣayẹwo iye eniyan ti awọn ọlọpaa ti mu nitori pe wọn kọlu, dẹruba, tabi fi ipa ba iyawo, ọrẹbinrin tabi ololufẹ wọn obinrin tẹlẹ lo pọ.

Gẹgẹ bi ohun ti alamojuto awọn to fara gba ẹgba iwa ipani England ati Wales, Same Vera Baird, ṣe sọ pe gbogbo wọn jẹ ọmọ iya.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ati pe, bo tilẹ jẹ pe ibaṣepọ wa laarin ọti lile, oogun oloro ati iwa ipa laarin ololufẹ, o ṣe pataki lati wo abajade iwadii yii daadaa.

Àkọlé fídíò, 'Ohun tóo gbúdọ ṣe lọ́dún yìí bí o bá fẹ́ kí Ọlọ́run bá ọ rìn'

O sọ pe "ọpọlọpọ to maa n lo iwa ipa pẹlu ololufẹ wọn ti wọn ba mu ọti yo, yoo tun ṣe bẹ ẹ ti ọti ba da l'oju wọn.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe