Camp Simba: Ènìyàn mẹ́ta sọ ẹ̀mí wọn nù lásìkò ìkọlù tó wáyé ní ibùdó ogun America

Awọn ọmọ ogun

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ ikọlu ni Al-Shabab ti ṣe ni ila oorun Africa.

Ọmọ ogun, ati oṣiṣẹ abaniṣiṣẹ meji ti to jẹ ọmọ ilẹ America padanu ẹmi wọn lasiko ti ikọlu waye si ibudo ọmọ ogun kan ni Kenya.

Ẹgbẹ ajijangbara ẹlẹsin Islam, Al-Shabab, lo wa lẹyin ikọlu naa to ṣe iku pa ninu awọn ọmọ ogun orilẹ-ede Kenya ati America ni agbegbe eti omi ni Lamu, l'ọjọ Aiku.

Ileeṣẹ ọmọ ogun America sọ pe awọn oṣiṣẹ meji miran tun farapa.

Olori ogun America nilẹ Africa, Ọgagun Stephen Townsend, sọ pe "Awọn ọmọ America to farapa ti n gbadun diẹdiẹ, a si ti ko wọn kuro ni ibudo."

Awọn ti ikọlu naa ṣoju wọn sọ pe awọn gbọ ìró ibọn, ti wọn si tun ri eefin dudu to n jade lati Ibudo Simba ni erekusu Manda.

Ọgagun Townsend fikun ọrọ rẹ ninu atẹjade naa pe awọn n gbadura fun awọn ẹbi ati ọrẹ awọn alajọṣiṣẹpọ awọn to padanu ẹmi wọn.

"Bi a ṣe n bu ọla fun irubọ wọn, naa ni a n tun ara mu.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Townsend ni: Awa pẹlu awọn alajọṣiṣẹpọ wa ni Africa ati nilẹ okeere yoo jọ lepa awọn to ṣe ikọlu yii, Al-Shabab ati awọn to n gbeero lati pa America ati afojusun rẹ lara.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Ileeṣẹ ologun Kenya sọ wi pe mẹrin lara awọn ajijangbara ẹlẹsin Islam naa ba iṣẹlẹ ọhun lọ, ati wi pe wọn ti pa ina to jo ni ibudo naa nitori ikọlu to waye.

maapu Kenya

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ikolu yii ba opo eeyan lokan je pupo

Al-Shabab ati awọn alakatakiti Al-Qaeda jọ n ṣiṣẹ pọ, olu ileeṣẹ wọn si wa ni orilẹ-ede Somalia to wa l'ẹgbẹ Kenya.

Àkọlé fídíò, Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Ọpọlọpọ ikọlu si ni ẹgbẹ naa ti ṣe ni agbegbe naa lati bi ọdun mẹwaa to ti bẹrẹ.

Eniyan mejidinlọgbọn lo ku lasiko ti ado oloro bu ni Mogadishu to jẹ olu ilu Somalia,

Àkọlé fídíò, 'Ohun tóo gbúdọ ṣe lọ́dún yìí bí o bá fẹ́ kí Ọlọ́run bá ọ rìn'