Qasem Soleimani: Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Iran ló jáde, àádọ́ta èèyàn ni wọ́n tẹ̀ pa níbi ìsìnkú tí kò wáyé mọ́

Awọn oludaro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Isinku ọgagun Iran, Qasem Soleimani ti ilẹ Amẹrika ṣekupa lọsẹ to kọja ko ni waye mọ loni ọjọ Iṣẹgun.

Okere tan aadọta eniyan lo papaoda nibi ti ọgọọrọ awọn ọmọ ilẹ Iran to le ni miliọnu ti tu jade lati ṣe isinku ọgagun wọn to ku ni ipaṣẹ ado oloro ti ilẹ Amerika ju lu wọn.

Iṣẹlẹ awọnn to di oloogbe yii lo jẹ ki wọn sun isinku naa siwaju.

Awọn oṣiṣẹ ijọba ilẹ Iran ṣalaye pe ijọba yoo ṣe ikede isinku Soleimani laipẹ yii.

Èèyàn márùn-úndínlójì kú lára àwọn tó ń ṣèdárò ọ̀gágun Qasem Soleimani

Okere tan eniyan to le ni marundinlogoji lo ti papaoda nibi ti ọgọọrọ awọn ọmọ ilẹ Iran to le ni miliọnu ti tu jade lati ṣe isinku ọgagun wọn to ku ni ipaṣẹ ado oloro ti ilẹ Amerika ju lu wọn.

Soliemani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin ni o le ni ogoji eniyan to ti farapa bayii nibi isinku ọhun ti wọn si ti ko wọn lọ fun itọju.

Àkọlé fídíò, BBC ṣe ìwádìí ipá àti agbára àwọn ọmọ ogun orilẹ-ede Iran lẹ́yìn tí wọn lérí si America lẹ́yìn ikú ọgagun Soleiman

Nibi isinku naa ni awọn miran ti papoda latari bi wọn ṣe n tẹ ara wọn mọlẹ nibi isinku naa.

Awọn oṣisẹ pajawiri ni awọn ko le e sọ iye eniyan to ku, amọ awọn eniyan kan ti papaoda nibi isinku naa.

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilu Kerman, ni wọn ti n sinku Qasem Soleimani, ti ọgọrọ miliọnu eniyan si ti wa ni ikalẹ lati ṣe idaro ọgagun wọn to lọ.

Iku ọgaagun naa ti da ipaya ati aibalẹ ọkan silẹ laarin orilẹede Amerika ati Iran nitori wọn ko rẹ tẹlẹ, ki Amerika to pa ọgagun wọn.

Ọpọ eniyan ri Soleimani gẹgẹ bi ẹnikeji to lagbara julọ lorilẹede Iran, lẹyin adari agba Ayatollah Khamenei.

Soliemani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ orilẹede Amerika ri gẹgẹ bi agbẹsunmọmi to ti ṣekupa ọgọrọ awọn ọmọ ilẹ Amerika.

Ado oloro ti ikọ Amerika ran si lo pa a ni orilẹede Iraq ni Ọjọbo pẹlu aṣẹ lati ọwọ aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump.

Ṣé lóòtọ́ ní agbára àti ipá àwọn ọmọ ogun Iran tó ó kojú tí America?

Iran ṣeleri lati gbẹsan lẹyin ti America pa Ogagun rẹ to gajulọ lorilẹ-ede naa, Qasem Soleiman pẹlu ado oloro ni papakọ ofurufu ni Baghdad, lorilẹ-ede Iraq.

Adari patapata lorilẹ-ede Iran, Ayatollah Ali Khamenei lo sọ bẹẹ lasiko to n daro Soleiman to di oloogbe.

Tehran, Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ṣé lóòtọ́ ní agbára àti ipá àwọn ọmọ ogun Iran tó kojú tí America?

Nitori naa, iru agbara wo ni Iran ni lati koju ilẹ Amerika ti wọn fẹ gbẹsan iku ọgaagun naa lori rẹ.

Bawo ni ikọ ọmọogun Iran ṣe tobi to?

Ilẹ iwe giga ti International Institute for Strategic Studies to wa ni Ilẹ Gẹẹsi ni ọmọogun ilẹ Iran to iye 523,000.

Eleyii ni 350,000 ninu wọn jẹ ọmọgun ilẹ orilẹ-ede naa, nigba ti 150,000 ninu wọn si jẹ ọmọogun ikọ Islamic Revolutionary Guards Corps (IRGC).

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni wọn ni ọmọogun oju omi, ti wọn n lo ọkọ oju omi fi ja ni agbegbe Strait of Hormuz, nibi ti ọpọlọpọ ọkọ oju omi ilẹ okeere ati Iran ti maa n koju ara wọn, paapa ni ọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

Ogoji ọdun sẹyin ni wọn da ikọ IRGC silẹ, ti wọn si n jẹ iranṣẹ fun adari patapata lorilẹ-ede naa.

Ikọ yii ma n ṣiṣẹ fun ilẹ Iran ni okeere lati ja ogun bonkẹlẹ fun orilẹ-ede naa.

IRGC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

N jẹ ṣẹ Orilẹ-ede Iran ni ado oloro ọlọgọọrọ?

Bẹẹ ni, Iran ni ado oloro ọlọgọọrọ, eleyii ti o le ṣọọṣẹ fun orilẹ-ede Isael ati Saudi Arabia.

Ile iṣẹ ọmọogun orilẹ-ede Amerika fi lede pe Iran lo ni ado oloro to le e ṣekupani lọgọọrọ "ballistic misile" julọ ni orilẹ-ede to wa ni Gbungun Ila-oorun agbaye (Middle East).

Iran

Ọdun 2015 ni orilẹ-ede Iran ṣe adẹhun Ajọ Iṣọkan lagbaye lati dẹkun ṣisẹ ado oloro ọlọgọọrọ, amọ ko han si gbangba boya wọn ti pada si ni si ni ṣẹ ado oloro naa pada.

Bakan naa ni Ilẹ Iran ni agbara ati ohun ẹlo ija lati ṣe ohun ija igbalode to le ṣekupani lọgọrọ, Nuclear Weapon, amọ ti wọn ko tii ṣe e jade.

Graphic showing Patriot system

Njẹ Iran ni ohun eelo ayelujara ti igbalode?

Lẹyin ti awọn kan ṣe akoba fun eto ohun eelo ibugbamu ọlọgọọrọ ti Iran ko jọ ni ọdun 2010 nipa lilo ẹrọ ayelujara, wọn ti ṣe ẹrọ igbalode wọn lati le gbogun ti iru iṣẹlẹ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'

Iwadii ni ikọ ọmọ ogun IRGC ni ohun eelo imọ ẹrọ ayelujara igbalode, ti wọn n ṣisẹ lori iwadii idakọnkọ ni okeere ati labẹlẹ.

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọdun 2012, orilẹede Amerika fi ẹsun kan Iran pe awọn lo wa nidi ikọlu awọn ohun elo ayelujara ti ile iṣẹ awọn banki ilẹ Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Bakan naa ni wọn fẹsun kan Iran ni ọdun 2019 pe wọn ṣe atako si ile iṣẹ imọ ofufufu ilẹ Amerika ati pe wọn ti ọwọ bọ eto idibo aarẹ ti ọdun 2019 to gbe Aarẹ Donald Trump wọle gẹgẹ bi aarẹ.

BBC Fact Reality Check

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?