Fake Kidnap: Ọlọ́pàá Eko ń wá arákùnrin tó parọ́ gba owó ìjínigbé 700k lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀

Aworan awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceng

Ọwọ palaba arabinrin kan to gbimọran pẹlu ọrẹkunrin r pe ko ji oun gbe ti ṣegi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lo kede ọrọ yi lasiko ti wọn ṣafihan awọn afunrasi ọdaran tọwọ tẹ fun orisi ẹsẹ.

Olumuyiwa Adejobi to jẹ alukoro ọlọpaa ni arabinrin Precious Chukwu ẹni ọdun mejilelogun ati Ujunwa Offiah jijọ lẹdi apo pọ pẹlu Ifesinachi Blessed lati parọ pe awọn ji Ujunwa gbẹ.

Ninu alaye rẹ, o ni Precious ati Ujunwa jẹ ọrẹbinrin si Ifesinachi to n ṣiṣẹ awakọ takisi Uber. Ifesinachi ti na papa bora bayi.

Olumuyiwa tẹsiwaju pe niṣe ni Ifesinachi gbe Ujunwa pamọ sibi kan to si pe awọn mọlẹbi rẹ pe ki wọn san ọgbọn miliọnu lati fi doola rẹ.

Lẹyin ọpọ atotonu, awọn mọlẹbi Ujunwa san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira fun Ifesinachi.

Iwadii ọlọpaa lẹyinwa ṣafihan pe arumọjẹ ijingbe lo waye ti wọn si gba Ujunwa ati Precious to ṣalatilẹyin fun Ifesinachi.

Lọwọlọwọ bayii, wọn ko mọ ibi ti Ifesinachi sa lọ ṣugbọn Ujunwa ati Precious tawọn mejeeji jẹ ọrẹbinrin Ifesinachi ti wa lahamọ ọlọpaa.

Yatọ si awọn afurasi yi ti wọn ṣafihan wọn, wọn tun fi arakunrin ogboju ọlọṣa kan Fatai Ismail han.

Aworan awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, LagosPoliceng

Fatai ti inagijẹ rẹ n jẹ 'small' ni wọn sọ pe o n damu awọn eeyan Langbasa ladugbo Ajah.

Alukoro ọlọpaa ni ọwọ ọlọpaa tẹ Fatai plu iranwọ awọn fijilante ati ara adugbo lasiko to lọ fọ ile itaja nla kan ni Ajah.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá