Ritual killer: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Codedwizzy
Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ afurasi ọkunrin kan, Owolabi Yusuf ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa akẹkọọ ile iwe giga gbogbonṣe kan, Toluwalase Kembi lati fi ṣe oogun owo.
Ohun ti a gbọ ni pe Kembi, ọmọ ogun ọdun ṣabẹwo si ọrẹkunrin rẹ ni Ikorodu eyi to sọ pe miliọnu meji owo naira loun gba lati fi ọmọdebinrin naa joogun.
Kembi to n gbe pẹlu awọn obi rẹ lagbegbe Tabon Tabon l'Agege pade iku ojiji lọjọ kejilọgbọn oṣu keje ọdun 2020 yii nigba to lọ sun nile Yusuf.
Yusuf ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ni iroyin sọ pe o pa Kembi ti o si ge wẹlẹwẹlẹ lati fi ṣe oogun owo.
Ẹbi ọmọdebinrin ọhun sọ fun awọn akọroyin pe ileeṣe ọlọpaa ẹkun Elere l'Agege ko ti gbe oku akẹkọọ naa fawọn.
Lẹyin ọsẹ mẹta ti Yusuf ṣiṣẹ laabi yii tan lọwọ awọn agbofinro too tẹẹ lẹyin to ti sa lọ siluu Ilorin nipinlẹ Kwara.
Afurasi ọhun ni a gbọ pe o jẹwọ fawọn ọlọpaa wi pe oun gbimọ pọ pẹlu awọn mẹta mii ninu eyi ti babalawo kan ti wọn n pe ni Owonikoko wa.
O ni babalawo ọhun gan an lo ni ki oun fi ọmọ oodo lu akẹkọọ naa pa to ba ti ṣabẹwo si i.
- Lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington, èmi làgbà kàn nínú iṣẹ́ orin Fuji- Obesere yarí
- Building Collapse: Iléèwé míràn tún dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko
- Yatọ̀ sí pé ó ṣe sọ́jà, tó tún jẹ́ ọkọ Oriṣabunmi, wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu
- Facebook mú àyípadà bá àtẹ̀jíṣẹ́ síra ẹni lórí òpó Instagram, wo àwọn ǹkan tó kàn ọ níbẹ̀
Kembi to ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye ''ND'' nile ẹkọ giga gbogbonṣe n mura lati lọ fun ẹkọṣẹ ohun to lọ ṣe nile ẹkọ giga fun ọdun kan ki o tun ṣagbako iku ojiji.
Oluwatoyin Kembi to jẹ baba akẹkọọ naa sọ fawọn akọroyin pe awọn tiẹ ro pe ọmọ naa ti sọnu ni nigba ti ko pada wale lọjọ naa lai mọ pe awọn oniṣẹ ibi ti gee wẹlẹ wẹlẹ.
Yusuf sọ pe babalawo nikan lo mọ ibi ti oku Kembi wa.
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi ti ṣalaye pe iwadii si n lọ lọwọ lati mu awọn mẹta yoku ti gbimọ pọ pẹlu Yusuf lati pa Kembi.
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
- ''Operation Burst'' ti mú Eji, tó gba ipò Ebila olórí ''One Million Boys'' ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Ilé ìjọsìn lè bẹ̀rẹ̀ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ padà, Mọ́sáláṣí àti Ṣọ́ọ̀ṣì lé gba iye èèyàn tó wù wọ́n ṣùgbọ́n...
- Obìnrin bíi Ruth Bader ni yóò gba ipò rẹ́ ní iléẹjọ́ tó gajùlọ nílẹ̀ Amerika- Donald Trump
















