Lagos School Building Collapse: Iléèwé míràn tún dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko

Ileewe

Ajọ oṣiṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti kede pe Ileewe kan ti wo ni agbegbe Ile Epo Bus Stop, Iyana Ejigbo ni ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ LASEMA, Nosa Okunbor lo fi lede bẹẹ.

Okunbor fikun pe ileewe girama ni ileewe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ileewe

Bakan naa lo dupẹ pe opin ọsẹ ni iṣẹlẹ naa waye, ti ko si si awọn ekẹkọọ ni ileewe lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Ileewe

Ajọ Pajawiri naa kesi awọn oṣiṣẹ rẹ ni agbegbe naa lati tete tara sasa lọ si ibẹ.

Ileewe

Ọpọlọpọ ile ibugbe lo ti wo ni ipinlẹ Eko lọpọ igba, to fi mọ awọn ileewe ati ileeṣẹ ati ibugbe.

Ileewe

Ti a ko ba gbagbe, Ọjọ Kọkanlelogun, Oṣu Kẹsan ni ijọba ipinlẹ Eko ni ki awọn ileewe ṣi pada lẹyin oṣu marun un ti wọn ti wa ni ile nitori ajakalẹ arun Coronavirus.