Edo Election 2020: Obaseki gba ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn

Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, Twitter/INEC Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ eleto idibo INEC ti fun Gomina Godwin Obaseki ni iwe-ẹri moyege lẹyin to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ EDo to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Obaseki fẹyin oludije APC, Osagie Ize-Iyamu gbalẹ ti o si ṣe bẹẹ wọle ibo gomina fun saa keji.

Gomina Obaseki to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lo ni ibo to pọju ninu idibo naa.

Kọmiṣọnna INEC fun ipinlẹ Edo, Rivers ati Bayelsa, Arabinrin May Agbmuche-Mbu lo fun ni iwe-ẹri ọhun lọjọ Iṣẹgun ni ilu Benin.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Agbmuche-Mbu ko ṣai lu gbogbo awọn ti ọrọ kan lọgọ ẹnu to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo fun aṣeyọri eto idibo ọhun.

Wo ìdí tí ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ṣe lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀

Godwin Obaseki wọle ibo gomina ipinlẹ Edo ninu eto idibo to lọ ni irọwọ-rọsẹ kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta.

Obaseki to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fẹyin oludije APC Osagie Ize-Iyamu gbalẹ ninu idibo ọhun ti o si wọle lẹẹkeji.

Osagie Ize-Iyamu ati Godwin Obaseki

Oríṣun àwòrán, Facebook/Godwin Obaseki

Ohun to ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe edto idibo naa lọ ni wọọrọwọ laisi rogbodiyan papaa julọ pẹlu gbọmisi omi o too to ti waye laarin laarin awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ṣaaju ibo naa.

Onwoye nipa eto idibo, Ọmọwe Dikrullahi Yagboyaju to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye ohun to ṣe okunfa alaafia to jọba ninu eto idibo gomina ipinlẹ Edo.

Ọmọwe Yagboyaju sọ pe nkan koko mẹta lo mu ki eto idibo Edo kẹsẹjari lai si rogbodiyan.

Ekinni ni pe gbangba laṣa ta ni eto iforukọsilẹ awọn oludibo, eto idibo, akojọpọ ibo ati ikede esi ibo,.

Àkọlé fídíò, Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Ọmọwe Yagboyaju ni eto idibo naa lọ ni irọwọ rọsẹ nitori gbogbo awọn ti ọrọ kan bi ajọ INEC, awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo tẹle alakalẹ ofin eto idibo.

O fikun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti awọn ti ọrọ kan ninu eto idibo ko ba ri ara wọn pe awọn ju ofin lọ, ko le si rogbodiyan ninu iru eto idibo bẹẹ.

Àjọ INEC ò gbọdọ̀ kéde pé ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo kò yanjú- Wike kìlọ̀

Alaga igbimọ ẹgbẹ oṣelu PDP to n ri si eto ipolongo eto idibo gomina ipinlẹ Edo to tun jẹ gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti kilọ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko maa kede wi pe eto idibo naa ko yanju.

Wike rọ ajọ INEC lati ṣe afihan ohun gbogbo ti wọn ba fẹ ṣe lori eto ibo gomina Edo lai fi igba kan bọkan ninu.

Gomina ipinlẹ Rivers ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo gbọdọ ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ ki wọn si maa faye gba ẹnikan kan lati da eto idibo naa ru.

Obaseki ati Ize- Iyamu

Oríṣun àwòrán, Obaaseki/Ize-Iyamu

Wike ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo ko si lọpọlọpọ ibudo ti wọn ti n ko esi idibo jọ eleyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.

Wike sọ pe oun nigbagbọ pe ajọ INEC ko ni ba orukọ ara jẹ, yoo si sẹ eto idibo naa ni aṣeyọri ti alakan n ṣe epo.

Lakotan, gomina ipinlẹ Rivers ni oun ti ẹgbẹ PDP ko fẹ gbọ ni pe ki INEC kede ibo gomina Edo pe ko fori sọ ibi kan.

Wo bí èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Edo ṣe ń jáde

Eto idibo ti pari ni ipinlẹ Edo bayii, ohun ti awọn oludibo atawọn onwoye n foju sọna fun bayii ni esi idibo lati mọ ẹni ti yoo maa ṣe akoso iṣejọba ni ipinlẹ naa fun ọdun mẹrin.

Edo

Wo bí ìfigagbágbá tani yòó di gómìnà Edo láàrin Obaseki àti Ize-Iyamu yóò ṣe lọ

O kere ta ijọba ibilẹ mejila ninu mejidinlogun to wa ni ipinlẹ ni yoo kopa ribiribi lonii lati yan ẹni ti yoo di gomina wọn gẹgẹ bi gomina to wa lori alefa lọwọlọwọ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ṣe maa gbena woju oludije ti ẹgbẹ oṣelu APC, Pasitọ Ize-Iyamu.

Bo tilẹ jẹ pe nibẹrẹ pẹpẹ, oludije mẹrinla lo wa ṣugbọn awọn oluwoye ti wo o fin fin pe gbogbo awọn toku ti bila to si ti ku ija laarin erin meji, PDP ati APC.

Awọn ijọba ibilẹ ti iroyin n s pe idibo oni yoo ti waye ni Egor, Ikpoba/Okha, Oredo, Ovia North-East, Ovia South-West, Uhunmwode, Akoko Edo, Owan West, Owan East, Etsako East, Etsako West ati Etsako Central.

Wo bí èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Edo ṣe ń jáde

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ idibo

Ẹgbe oṣelu Peoples Democratic party ti ni ki awọn ọlọpaa jawọ ninu idunkoko mọ awọn Gomina ẹgbẹ naa to wa ni ipinlẹ Edo fun idibo Gomina nibẹ.

Ninu atẹjade kan ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Kola Ologbondiyan fi sita o ni iwa yi ko bojumu nitori awọn ọlọpaa ko dẹgun le awọn Gomina APC to wa fun idibo Edo.

Ologbondiyan to ni alaga ẹgbẹ Uche Secondus koro oju si iwa awọn ọlọpaa yi ni ọna lati da wahala silẹ ni wọn n ba bọ.

Atẹjade lati ọdọ ẹgbẹ PDP

Oríṣun àwòrán, PDP

Pdp sọ pe o jẹ iyalẹnu fawn pe awọn ọlọpaa ko de ọdọ awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu APC bi Gomina Abdullahi Ganduje ti Kano ati akẹgbẹ rẹ Hope Uzodinma ipinlẹ Imo.

Wọn ni bẹẹ naa ni igbakeji aar ile aṣofin agba Sẹnetọ Ovie Osagie naa n yan fanda kiri ile alaga ẹgbẹ APC tẹlẹ Adams Oshiomole.

Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti fesi sọrọ yi bẹẹ naa si ni APC naa ko ti fesi.

Idibo Gomina ipinlẹ Edo yoo waye lọjọ Kọkandilogun oṣu Kẹsan nibi ti Gomina Godwin Obaseki ati Pasitọ Ize-Iyamu yoo ti jọ maa figa gbaga.