Edo Election 2020: Ààrẹ Buhari, Atiku àti àwọn èèkàn ìlú míràn ti n kí Obáseki ku oriire

Oríṣun àwòrán, Obaseki/ Twitter
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ránṣe kú orííre si Godwin Obaseki lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà tó wáye lónìí nípìnlẹ̀ Edo.
Obaseki to jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fi ìdí akẹgbẹ́ rẹ̀ labẹ̀ ẹgbẹ òṣèlú APC jánlẹ.
Nínú àtẹjáde ti Garba Shehu tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ Buhari lórí ìpolongo fi sita, aarẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn elétò ìdìbò fún bi wọ́n ṣe ṣeto idibo naa nirọwọrọsẹ.
- Obaseki la Ize-Iyamu mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo
- ''Operation Burst'' ti mú Eji, tó gba ipò Ebila olórí ''One Million Boys'' ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington, èmi làgbà kàn nínú iṣẹ́ orin Fuji- Obesere yarí
- Ọ̀tọ̀ lórìn bi wọ́n ṣe yan àwọn ti yóò kúrò nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà BB Naija lónìí
Ó fí kún-un pé èyi tọka si àrídáju pé ìjọba ààrẹ Buhari nígbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò ti kò ni kọ́nukọ́họ nínú.
Bákan náà lo fi ọ̀rọ̀ ránṣe si pé, kó ri àṣeyọri rẹ̀ gẹgẹ bi anfaani lati fi ọkan idupẹ àti ìrẹ̀lẹ̀ han
Bákan náà ni igbákeji ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan rí Atiku Abubakar náà ti gboriyin fún àwọn ènìyàn ìpinlẹ̀ Edo fún iṣẹ rere ti wọ́n ṣe láti gbé Obaseki wọlé fún sáà keji.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Atiku ni Agbara àwọn bàbá ìṣàlẹ̀ ti dópin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáye ni ìpińlẹ̀ Edo lónìí àti pé agbára kan ti yóò dúró náà ni àgbàra àwọn oludibo.

Oríṣun àwòrán, Nysome Wike/twitter
Atiku rọ àwọn ènìyàn ìpińlẹ̀ Ondo láti gba ara wọ́n kúrò lọ́wọ́ bàbá ìsàlẹ̀ bi àwọn ènìyàn Edo ṣe ṣe.
Kò tán síbẹ̀, Gómìnà ìpińlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike náà wa lára àwọn to kọ́kọ́ ki Obaseki ku oríire ìjáwé olúborí.
Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpińlẹ̀ Edo fún àdúrò ti wọ́n àti pé òun ni ìgbàgba pé bí òun ṣe n kúro ni Edo báyìí òun mọ̀ pé, Obaseki yóò ṣe ìtójú wọ́n dáradára.

Oríṣun àwòrán, @Seyi Makinde
Gómìnà ìpińlẹ̀ Oyo Seyi Makinde ko gbẹ́yìn lára àwọn tọ kọ́kọ́ ki gómìnà Obaseki àti igbákeji rẹ̀, Phillip Shaibu ku oríire àṣeyọri ìdìbò.
Godwin Obaseki wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Godwin Obaseki
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii lo sọ wi pe Godwin Obaseki lo wọle ibo gomina ipinlẹ Edo.
Eyi tumọ si pe Obaseki to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fẹyin oludije APC Osagie Ize-Iyamu gbalẹ ninu idibo ọhun.
Ni bayii, Gomina Obaseki ti wọle gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Edo fun saa keji.
- Wo bí èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Edo ṣe ń jáde
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
- Lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington, èmi làgbà kàn nínú iṣẹ́ orin Fuji- Obesere yarí
- Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná
- Iléèwé míràn tún dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko
- Ọkùnrin kan tún pa ọmọ rẹ méjì àti ìyá tó bíi
Obaseki jawe olubori ni ijọba ibilẹ to pọju ninu ibo naa ti Ize-Iyamu si te le e.
Ọga ajọ INEC for eto idibo gomina ipinlẹ Edo, Ọjọgbọn kpofure Rim-Rukeh lo kede Obaseki gẹgẹ bi ẹni to wọle ibo ọhun.
Ṣaaju ni Obaseki fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ PDP lẹyin ti o fidi rẹmi ninu idibo abẹle fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC.
Ẹwẹ, iyanlẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ pe Gomina Obaseki lo jawe olubori ni ijọba ibilẹ alako rẹ, Ize-Iyamu.
Lakotan, oludije PDP Obaseki ni ibo 307,955 nigba ti Ize-Iyamu si ni ibo 223,619 ninu ibo naa.












