Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Twitter/@ahmad
Ileeṣẹ agbonfinro ṣeria, Hisbah nipinlẹ Sokoto ti mu afurasi mẹta lori ẹsun pe wọn pin fọnran kan nibi ti wọn ti n dunkoko mọ ọmọdebinrin ọdunmẹrindinlogun kan lati fipa ba a lopọ.
Ọmọdebinrin naa ni a gbọ pe o mura lati ṣe igbeyawo lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2020 yii tẹlẹ.
Ṣugbọn o wọgile igbeyawo ọhun nitori fidio tawọn afurasi naa pin kaakiri ori ayelujara.
- Ọ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?
- Háà Ibadan! Obìnrin tó bá fẹ́ wọn, igbó Sambisa ló lọ - Lizzy Anjorin
- Afipábánilòpọ̀ méjì tún ṣọṣẹ́ lára ọmọ ọdún 17 l'Ekiti
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Ẹ̀wọ̀n gbére ni fún ẹnikẹ́ni tó bá fipá bánilòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
Ọga awọn agbofinro Hisbah nipinlẹ Sokoto, Ọmọwe Adamu Kasarawa sọ fawọn akọroyin wi pe ọmọ eekan lagbo oṣelu ni ọkan lara awọn afurasi mẹta ọhun.
O ni awọn ti pari iwadii lori iṣẹlẹ naa, wọn o si foju ba ileẹjọ laipẹ.
Mama ọmọdebinrin naa ṣalaye pe lọdun 2017 ni ọkan lara awọn afurasi fipa ba ọmọ oun lopọ nigba to wa lọmọ mọdun mẹrindinlogun.
Iya ọmọ naa sọ pe ọdọkunrin naa fi fọnran ifipabanilopọ ọhun pamọ fun ọdun mẹta lati ba ọmọ ohun laye jẹ ni.
- Ìdájọ́ ikú ni a fẹ́ fún àwọn afipábánilòpọ̀ - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn
- Báyìí ni ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn ṣe pè fún ìdájọ́ ikú fún àwọn afipábánilòpọ̀
- Kanye West ṣèrànwọ́ $2m fún ẹbí George Floyd, yóò tún rán ọmọ rẹ̀ nílé ìwé
- Afipábánilòpọ̀ méjì tún ṣọṣẹ́ lára ọmọ ọdún 17 l'Ekiti
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Ẹ̀wọ̀n gbére ni fún ẹnikẹ́ni tó bá fipá bánilòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
''Ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2020 yii ni ẹnikan ṣadeedee pe mi ti o si sọ fun mi pe oun ri fọnran kan kan ninu eyi ti Baffa Hayatu Tafida ti n fipa ba ọmọdebinrin lopọ,'' mama ọmọ naa lo sọ bẹẹ.
O ni afurasi naa tun fi fidio yii ranṣẹ si afẹsọna ọmọdebinrin yii atawọn mii lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mama ọmọdebinrin naa ṣalaye pe fidio yii gan an lo jẹ ki afẹsọna ọmọbinrin yii sọ pe oun ke ṣe mọ.
Mama ọmọbinrin sọ pe lọpọ igba ni baba Tafida ti gbiyanju lati fa oju ọmọ oun mọ ra ki o le gbagbe ẹjọ naa.
Baba ọmọ ni lootọ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, amọ oun ko figba kan dunkoko iku mọ iya ọmọdebinrin ọhun ko le fagile ẹjọ naa.
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ elétò ìlera, ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́- JOHESU
- Bí PDP ṣe na APC lálùbami ní Edo, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀ ní Ondo- PDP
- Wo ìdí tí ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ṣe lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀















