Say no to rape: Ìdájọ́ ikú ni a fẹ́ fún àwọn afipábánilòpọ̀ - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn

Awọn olufẹhonuhan

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan bii mẹrinla ọtọọtọ ti koro oju si iwa ifipabanilopọ ati iṣekupani ti awọn obinrin n koju lawujọ.

Ninu ipade awọn oniroyin to waye lopin ọsẹ yii niluu Ibadan, awọn ẹgbẹ naa gbarata lori iwa ọdaran ti awọn amokunṣeka kan n hu si ọmọde ati awọn agba to jẹ obinrin, paapa julọ lori ọrọ iṣekupani ati ifipabanilopọ.

Ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ naa, Arabinrin Grace Oluwatoye kesi ijọba ati awọn agbofinro lati bojuto wahala ti awọn ọmọbinrin n dojukọ lasiko yii.

O ni awọn ọmọbinrin bii mẹta ọtọọtọ to padanu ẹmi wọn nitori ifipabanilopọ ati iwa ipa laarin ọsẹ kan ti fa aibalẹ ọkan fun gbogbo abiyamọ pata.

Oluwatoye ni ohun to n kọnilominu ni wi pe awọn obinrin ti o jẹ wi pe lati ara wọn ni gbogbo eniyan ti jade naa lotun wa n koju iru wahala bayii. Gbogbo eleyii ko si sẹyin eto aabo to mẹhẹ lawujọ.

O ni aifi ẹnikankan jofin lo faa ti awọn olubi ẹda naa fi n tẹsiwaju ninu iwa ọdaran. Igbagbọ ẹgba naa ni wi pe igbẹsẹ lati dẹkun iwa ibajẹ naa yoo yan kankan ti ijọba ba bẹrẹ sini ṣe idajọ iku fun ẹnikẹni ti wọn ba gbamu.

Awọn ẹgbẹ naa tun fi ẹsun kan awọn obinrin to n ta oti lile ati paraga wi pe awọn naa lọwọ si ọrọ ifipabanilopọ yii nitori pe gbogbo nnkan buruku ti awọn ọdaran naa n mu lo n fun wọn ni igboya lati ṣiṣẹ ibi. Wọn ni "ẹni ti ko mu ọti lile ko ni ba ọmọ ọdun mẹrin si mẹjọ sun".

Awọn olufẹhonuhan

Wọn ke si ijọba lati ri si ọrọ awọn obinrin to n ta paraga lawọju ki adinku le de ba ipa buburu ti imukumu n ko laarin wa.

Lara ohun ti wọn tun kesi ijọba lati ṣe ki iwa ọdaran naa le kasẹ nilẹ ni agbekalẹ ofin ti yoo maa da sẹria fun awọn afiabanilopọ, ati ibawi to peye fun gbogbo ẹni ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori.

Arabinrin Oluwatoye tun rọ awọn onile iṣẹ igbohun safẹfẹ lati maa fi aye ilanilọyẹ silẹ lori awọn eto ti wọn n ṣe oye tun bọ le ye awọn ara il sii lori awọn ewu to rọ mọ ifipabanilopọ ati iṣekupani lawujọ wa.

Àkọlé fídíò, #JusticeforTina: Àwọn obi Tina Ezekwe ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo pẹ̀lú omijé lójú

Ọkan lara awọn ọkunrin to jẹ aṣoju ẹgbẹ naa, Arakunrin Hamzat Kọlawọle so wi pe iwa ti ko bojumu t ko si yẹ awujọ ni iwa ifipabanilopọ.

O ni ọkunrin to ba fi ipa ọmọde tabi agbalagba to jẹ obinrin lopọ ti ṣe ohun buruku.Kọlawọle ni ko yẹ ki a bi iru awọn ẹda bẹẹ si aye rara de ibi wi pe a o maa pe wọn ni ọkunrin.

O ni iru awọn ọkunrin to n hu iru iwa ọdaran bẹẹ lo yẹ ki gbogbo awọn ọkunrin to ku pawọpọ lati bawi nitori wọn ba gbogbo ti ko mọwọmẹsẹ loju jẹ.

A kò tíì lè sọ ti ìfipabánilòpọ̀ àmọ́ òkúta ni wọ́n fi fọ́ orí Azeezat - Ọlọ́pàá Oyo

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan bii mẹrinla ọtọọtọ ti koro oju si iwa ifipabanilopọ ati iṣekupani ti awọn obinrin n koju lawujọ.

Ninu ipade awọn oniroyin to waye lopin ọsẹ yii niluu Ibadan, awọn ẹgbẹ naa gbarata lori iwa ọdaran ti awọn amokunṣeka kan n hu si ọmọde ati awọn agba to jẹ obinrin, paapa julọ lori ọrọ iṣekupani ati ifipabanilopọ.Ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ naa, Arabinrin Grace Oluwatoye kesi ijọba ati awọn agbofinro lati bojuto wahala ti awọn ọmọbinrin n dojukọ lasiko yii.

O ni awọn ọmọbinrin bii mẹta ọtọọtọ to padanu ẹmi wọn nitori ifipabanilopọ ati iwa ipa laarin ọsẹ kan ti fa aibalẹ ọkan fun gbogbo abiyamọ pata.

Oluwatoye ni ohun to n kọnilominu ni wi pe awọn obinrin ti o jẹ wi pe lati ara wọn ni gbogbo eniyan ti jade naa lotun wa n koju iru wahala bayii. Gbogbo eleyii ko si sẹyin eto aabo to mẹhẹ lawujọ.

O ni aifi ẹnikankan jofin lo faa ti awọn olubi ẹda naa fi n tẹsiwaju ninu iwa ọdaran. Igbagbọ ẹgba naa ni wi pe igbẹsẹ lati dẹkun iwa ibajẹ naa yoo yan kankan ti ijọba ba bẹrẹ sini ṣe idajọ iku fun ẹnikẹni ti wọn ba gbamu.

Awọn ẹgbẹ naa tun fi ẹsun kan awọn obinrin to n ta oti lile ati paraga wi pe awọn naa lọwọ si ọrọ ifipabanilopọ yii nitori pe gbogbo nnkan buruku ti awọn ọdaran naa n mu lo n fun wọn ni igboya lati ṣiṣẹ ibi. Wọn ni "ẹni ti ko mu ọti lile ko ni ba ọmọ ọdun mẹrin si mẹjọ sun".

Awọn olufẹhonuhan

Wọn ke si ijọba lati ri si ọrọ awọn obinrin to n ta paraga lawọju ki adinku le de ba ipa buburu ti imukumu n ko laarin wa.Lara ohun ti wọn tun kesi ijọba lati ṣe ki iwa ọdaran naa le kasẹ nilẹ ni agbekalẹ ofin ti yoo maa da sẹria fun awọn afiabanilopọ, ati ibawi to peye fun gbogbo ẹni ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori.

Arabinrin Oluwatoye tun rọ awọn onile iṣẹ igbohun safẹfẹ lati maa fi aye ilanilọyẹ silẹ lori awọn eto ti wọn n ṣe oye tun bọ le ye awọn ara il sii lori awọn ewu to rọ mọ ifipabanilopọ ati iṣekupani lawujọ wa.Ọkan lara awọn ọkunrin to jẹ aṣoju ẹgbẹ naa, Arakunrin Hamzat Kọlawọle so wi pe iwa ti ko bojumu t ko si yẹ awujọ ni iwa ifipabanilopọ.

O ni ọkunrin to ba fi ipa ọmọde tabi agbalagba to jẹ obinrin lopọ ti ṣe ohun buruku.Kọlawọle ni ko yẹ ki a bi iru awọn ẹda bẹẹ si aye rara de ibi wi pe a o maa pe wọn ni ọkunrin.O ni iru awọn ọkunrin to n hu iru iwa ọdaran bẹẹ lo yẹ ki gbogbo awọn ọkunrin to ku pawọpọ lati bawi nitori wọn ba gbogbo ti ko mọwọmẹsẹ loju jẹ.

Awọn iwa ipa si obinrin

Oríṣun àwòrán, Other

A kò tíì lè sọ ti ìfipabánilòpọ̀ àmọ́ òkúta ni wọ́n fi fọ́ orí Azeezat - Ọlọ́pàá Oyo

Mẹwaa n ṣẹlẹ ni duniyan, kayefi nla mii tun ṣẹlẹ. Abilekọ ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Azeezat Dhikirullahi to jẹ oloyun oṣu meje ni wọn ṣaa dede ba oku rẹ nilẹ ninu yara rẹ ti wọn ti fọ ori rẹ.

Iṣẹlẹ yii waye niluu Ijedun, abule kan lẹbaa Ojoo, Ibadan nipinlẹ Oyo. Ohun taa gbọ ni wi pe awọn to ṣe ọṣẹ yii fẹ fi obinrin naa ṣe ogun owo ni.

Ọjọ mẹrin ṣaaju iṣẹlẹ eleyi ni iroyin ti ọmọ ọdun mọkandinlogun kan, Barakat ti wọn fipa ba lo pọ ti wọn tun pa a ṣẹlẹ ni agbegbe Akinyele nilu Ibadan kan naa.

Ni ti Azeezat, iroyin sọ pe alaga ẹgbẹ awọn onile ni Ijefun, Alhaji Taiwo Adeyemo ṣalaye pe okuta nla ni wọn fi fọ ori rẹ ninu yara rẹ. O fi kun un wi pe oloogbe ṣẹṣẹ rinrinajo de lati ipinlẹ Kano ninu oṣu keji ni nibi ti ọkọ rẹ, Dhikirullahi ti ṣẹṣẹ ri iṣẹ lẹyin ọdun kan eto agunbanirọ rẹ.

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ pe ootọ ni wọn fi okuta fọ ọ lori. Nigba ti ikọ ọlọpaa debẹ, wọn ri i pe ko si ẹmi kankan lara rẹ mọ wọn si gbe e lọ si ile igboku si.

Lẹyin eyi ni kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Nwachukwu Enwonu atawọn lọga lọga ọlọpaa ni ipinlẹ naa kọwọ rin pẹlu awọn aṣoju gomina lọ ba idile oloogbe kẹdun ti wọn si ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ yii ni yoo bọ sọwọ ofin.

Loju ẹsẹ ni wọn si bẹrẹ igbesẹ iwadi lori ọrọ naa gẹgẹ bi ọga awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe ti gun le iṣewadii.

Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọlọpọ ileeṣẹ iroyin lo n gbe e safẹfẹ pe yatọ fun okuta ti wọn fi fọ ọ lori, wọn tun fipa ba a lo pọ, alukoro ọlọpaa sọ fun BBC Yoruba pe, awọn ko le fi idi eleyii mulẹ ṣugbọn iwadi ti wọn n ṣe ni yoo boya lootọ ni tabi irọ ni pe wọn tun fipa ba oloogbe aboyun yii lajọṣepọ.