Say no to rape: Ọmọ ọdún 17 tó ń kiri omi inú ọ̀rá fara kásáa ìfipábánilòpọ̀ l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Rolling stone
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ awọn afurasi afibanilopọ meji ni ibamu pẹlu ẹsun pe wọn fipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan lo pọ.
Ijọba ipinlẹ Ekiti fi eyi lede loju opo Twitter gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe n polongo lodi si iwa ifipabanilopọ pẹlu #saynotorape to gba gbogbo ayelujara kan.
Ko tii ju ọsẹ kan lọ rara bayii ti iru iṣẹlẹ yii bẹrẹ si ni gbode kan kaakiri Naijiria. Ọtọ ni ti Uwaila Omozuwa to waye ni ilu Benin, ko pẹ o tun ṣẹlẹ si Barakat ni ilu Ibadan.
Ọwọ sinkun ọba ti tẹ afurasi meji kan to fipa ba ọdọbinrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ipinlẹ Ekiti.
Asojukọroyin to wa nibẹ sọ fun BBC Yoruba pe ni ọja'ba tii ṣe gbajugbaja ọja nilu Ado Ekiti ni ọdọbinrin yii ti n ta omi inu ọra ti awọn ọkunrin meji to di kaka di kuku ṣa dede ke e lọna ti wọn si fi tipa tipa ba a lajọṣepọ ni sisẹ n tẹle.
Ṣugbọn ni bayii, ọwọ palaba wọn ti segi bi awọn ọlọpaa ṣe mu wọn.
Awọn eeyan gbe ọmọ naa lọ si ile iwosan lẹyin naa lawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ti ni awọn yoo ṣe ọfintoto iṣẹlẹ ọhun awọn aṣebi yoo si foju wina ofin.
Bakan naa, ijọba ipinlẹ Ekiti ti ni igbimọ to n ṣiṣẹ lodi si gbogbo iwa aburu si takọ-tabo yoo dawọ iṣẹ le ọrọ ifipabanilopọ yii.













