Lizzy Anjorin: Ibadan ní ọkọ mi, ata wíwẹ́ lo fẹ́ràn

lizzy Anjorin Lawal

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy Anjorin Lawal

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin oṣu meji to ṣe igbeyawo, o dabi ẹni pe gbogbo afẹfẹ-yẹyẹ igbeyawo ti dopin bayii fun gbajugbaja oṣere tiata ati eekan ori ayelujara, Lizzy Anjọrin.

Gẹgẹ bi ọrọ kan to fi sita loju opo Instagram rẹ, Lizzy Anjọrin ni oun ti n foju wina ipenija igbeyawo bayii, paapaa julọ igbeyawo pẹlu ọkọ oun to jẹ ọmọ ilu Ibadan.

Awada ni eekan ori ayelujara naa fi ọrọ naa ṣe, amọ otitọ pupọ lo sodo sinu ọrọ naa.

Lizzy ni oju oun ti n ri mabo gẹgẹ bi iyawo Ibadan nitori dipo ki ọkọ oun, Alhaji Lawal maa beere fun burẹdi ati tii gbigbona gẹgẹ bi ounjẹ aarọ, awọn ounjẹ ibilẹ bii Ekuru ati ata ti wọn fi ọwọ lọ, irẹsi ọfada ati ata ṣiṣa ati bẹẹbẹẹ lọ, lo n beere.

lizzy Anjorin Lawal

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy Anjorin Lawal

Eyi gan an lo mu ki Lizzy Anjọrin aya Lawal figbe bọnu lori ikanni ayelujara rẹ pe, ẹni ba fẹ ọmọ Ibadan, bi ẹni morile igbo Sambisa nibi ti awọn agbebọn Boko Haram fikalẹ si ni.

O fikun pe ọkọ oun ko mọ awọn ounjẹ alakọwe jẹ ayafi ounjẹ awọn alalẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ naa ni Lizzy tun ti fi imọran sọwọ sawọn omidan ti ko tii lọkọ pe, eyi ti ko ba lee ṣe wahala ina dida fun ọkọ rẹ, to jẹ pe ọkọ burẹdi ati tii lo fẹ fẹ, ko sare lọ fẹ oyinbo ni o, ko maa da laba lati fẹ ọmọ Ibadan rara.

Nigba ti Lizzy yoo pari ọrọ rẹ naa, o ni gbogbo awọn to n pariwo pe ki oun lọ fẹ ọkọ nigba naa, ni isisinyi ti oun n foju ko oro atarodo soju, oun o ri ẹnikẹni ninu wọn mọ o.

lizzy Anjorin Lawal

Oríṣun àwòrán, Instagram/lizzy Anjorin Lawal

Ẹ jẹ ka wo bi o ṣe kọ ọrọ rẹ naa:

"Ẹyin apọn, ẹ gbiyanju ki ẹ fẹ oyinbo ti yoo maa jẹ burẹdi ati tii lowurọ.

Ẹni ba fẹ ọkọ ni Ibadan bi igba to lọ si igbo Sambisa ni.

Ki le fe je sir ?

Ekuru pẹlu Ata ti won fi owolo,

Ofada pẹlu Ata ṣiṣa

Amala gbegiri Ewedu

Ewa aganyin pẹlu ata dindin

Iyan ti won fi odo gun.

Lọ f'ọka, lọ f'ọkọ emi nikan ni mo n foju wina rẹ pẹlu atarodo loju mi bayii o, kaluku yin wa nibi tẹẹwa bayii ẹ n gbadun aye yin

Tiyin naa fẹrẹ de, ṣe ẹ gbọ"

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Afi suuru.

Àkọlé fídíò, Bí rere ni àbí búburú, wo ohun tí Covid-19 leè ṣe sí àgọ́ ara rẹ