Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Wo àwọn òṣèré Tíátà t'ọ̀rọ̀ ìjà ta mọ́ etí aṣọ wọn tẹ́lẹ̀ rí

Oríṣun àwòrán, Other
Bi ti n ri, laipẹ ni gbọnmi si i omi o to o tun bẹ silẹ lagbo ere tiata Yoruba laarin molumọka oṣere to ṣẹṣẹ di iya aburo, Toyin Abraham ati akẹgbẹ rẹ Lizzy Anjorin.
Ni kete ti Toyin Abram bimọ tan naa ni ọrọ yọju lorii "maa ki ọ, mi o ni ki ọ ku ewu ọmọ" to tẹnu Lizzy jade lẹyin eyi si ni ọpọlọpọ ọrọ wiwu sita, titọwọ agbẹjoro bọ ọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọ ọ.
Ẹwẹ, kii ṣe ọrọ oni tabi ana ni iru iṣlẹ bayii ti n waye laarin awọn oṣere Yoruba ni Naijiria ko da nigba miiran, kii ṣe laarin awn ọdọ nikan fun idi kan tabi omiran.
Ero to wa jẹyọ ni pe ninu eyi to n ja rayin-rayin lọwọ lọwọ to ti di rangbọndan bayii ati awọn to ti waye tẹlẹ ri, ewo lo le ju?
Wumi Toriola ati Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toriola
Lara ọ̀rọ̀ to jẹ okunfa ija laarin Wumi Toriola ati Toyin Abraham ni awuyewuye pe ọrẹ Wumi iyẹn Seyi Edun gba ọkọ ti Toyin Aimaku n fẹ tẹlẹ, Adeniyi Johnson.
Wumi Toriọla, tíí se òsèré tíátà lóbìnrin, sọ fún BBC Yorùbá ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ìpa tó kó nínú ìgbeyàwó Toyin Abraham pẹ̀lú Adeniyi Johnson, lati ri pe o tọjọ, amọ tó papa forí sánpọ́n tori oun nawọ iranwọ́ ṣugbọn epe ni Toyin gbe oun ṣẹ.
Lati igba naa ni gbọnmi si i omi ko ti to laarin awọn mejeji ti Wumi si jẹ́ ki araye mọ pe Toyin kii ṣe ọga oun, kii si ṣe fiimu rẹ lo gbe ohun dide.
Laipẹ yii ti Toyin Abraham bimọ fun ọkọ ti o ṣẹṣẹ fẹ, Kolawole Ajeyemi ni iroyin kan tun ru sita pe lootọ Wumi ki oun ati ọkọ rẹ ku ewu ọmọ amọ ko pẹ rẹ lọrọ ija ranpẹ mii tun suyọ.
Baba Wande ati Tunde Kelani

Oríṣun àwòrán, KAREEM ADEPOJU
Nigba diẹ sẹyin, ariyanjiyan bẹ́ẹ́ 'lẹ̀ lori ẹni to ni fiimu ‘Ti Olúwa nilẹ̀’ ti ‘Mainframe’ gbe jade lọdun 1993, Tunde Kelani pẹlu Kareem Adepoju ti gbogbo eniyan mo si ‘Baba Wande’, ti Tunde Kelani si se olootu rẹ.
Iwe Iroyin kan sọ pé Baba Wande fẹsun kan Tunde Kelani wi pe owo to tọ si oun, kọ ni wọn fun oun lori fillmu naa ti o si jẹ wipe oun lo kọ itan naa.
Gbajugbaja olosere Tunde Kelani sọ wi pe irọ ni ọrọ ti Baba Wande sọ wi pe o yan oun jẹ, lori owo to san fun un lorii fiimu naa.

Oríṣun àwòrán, TKelani
Tunde Kelani ba BBC sọrọ wi pe oun ko yan Baba Wande jẹ, ati wi pe ẹtọ rẹ lohun fun un lẹyin ti won gbe fiimu naa jade.
Ṣugbọn a pada gbọ wi pe ọrọ naa ti yanju laarin agba oloṣere mejeji yii ti wọn si ti n mura igbesẹ itẹsiwaju fiimu 'Ti Oluwa nilẹ'.
Ronke Oshodi Oke ati Liz Anjorin

Oríṣun àwòrán, Ronke Oshodi Oke
Ija bóóde nitori pe gbajugbaja oṣere, Ronke Oshodi Oke bu ẹnu atẹ lu ki awọn oṣere maa gbe aye ati aṣeyori wọn si ori ẹrọ ayelujara.
Eyi ni ṣe pẹlu ṣiṣe afihan ohun ini tabi ohun tuntun ti awọn oniṣẹ tiata, ba dawọ le laye wọn lori ẹrọ ayelujara faraye gbọ.
Liz Anjorin ko fara mọ iha ti Ronke Oshodi Oke kọ si ọrọ yii rara o si wọn esi fun rẹpẹtẹ lọrọ ọhun ba di rẹpẹtẹ mọ wọn lọwọ titi to fi pada rọlẹ.
Fathia ati Saheed Balogun

Oríṣun àwòrán, Fathia Williams Balogun
Lẹyin igbeyawo to bi ọmọ meji, wọn tapo ija si ara ifẹ laarin tọkọ taya oṣere, Saheed ati Fathia Balogun.
Gẹg bi a ṣe gbọ, o to ọdun mẹtala ti ija wọn ti bẹrẹ. Gẹgẹ bi Fathia ṣe gbagbọ, ifura aijolootọ sira ẹni to jẹ kulẹ kulẹ ija wọn gan wa latọwọ oriṣiriṣi iroyin ti awọn oniroyin n gbe kiri eyi ti ko si jẹ ko tilẹ roju mojuto igbeyawo rẹ.
Ija yii fẹ loju gan to jẹ awọn mejeji a fi saa diẹ tun wu ara wọn, to ba ya a si tun ka kuro tititi ti wọn fi papa pinya.
Ẹwẹ, Fathia gbe fiimu kan jade laipẹ eyi to mu ohun ati Saheed Balogun ko'ra wọn loore koore gẹgẹ ajumọ ṣere ifẹ pọ lori itage.
Eyi ti mu ki ọpọlọpọ wa bẹrẹ si ni ro meni meji pọ pe ọkọ ati aya ti pada fa oju ara wọn mọra.
Mercy Aigbe ati Lauretta Sawyer

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe
Ẹni to ba oṣere Mercy Aigbe ni isọrọ n gbesi yii kii ṣe oṣere bi ko ṣe ni kan to fi ẹsun kan ni nkan bi ọdun to kọja lori ẹrọ ayelujara pe aṣọ igbeyawo oun ni Mercy Aigbe wọ fi ṣe ọjọ ibi.
Mercy Aigbe ninu esi tirẹ ni jẹjẹ oun loun n mura ọjọ ibi to si fẹ ya ọpọlọpọ fọto gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe lode oni ṣaaju ọjọ naa pẹlu oriṣiriṣi aṣọ to rẹwa ti aṣara loge oun si gbe aṣọ ti oun sanwo fun ranṣẹ si oun.
Arabinrin to fẹsun kan yari kanlẹ ti ọ̀rọ̀ naa si di tọrọ fọn kalẹ.
Kunle Afolayan ati Aremu Afolayan

Oríṣun àwòrán, Kunle Afolayan
Ko fibẹẹ kii n ṣe ija a n yọ ẹṣẹ tira ẹni tabi a n tabuku tabi sọko ọ̀rọ̀ sira ẹni loun to waye laarin tẹgbọn taburo ọmọ Afolayan, Kunle atu Aremu.
Ẹwẹ, awọn ololufẹ awọn mejeji lo n fi ọrọ sita nigbakuugba ti ọrọ ba jade lẹnu ọkan ninu wọn to jẹ ọrọ to lee fa wahala.

Oríṣun àwòrán, Aremu Afolayan
Nigba ti awọn mejeji si jọ ara wọn bi ẹpa, a maa dija laarin awọn ololufẹ wọn ti awn kan a ni Kunle ni, igun mii a ni Aremu ni.
Ẹwẹ, ni ọpọlọpọ igba, eyi ẹgbọn Kunle a da ara rẹ yọ sọtọ pe ohun kọ o, aburo oun lo sọrọ.














