Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Kolawole Ajeyemi ní kò dára kí àwọn òṣèré máa bú ara wọn lórí ẹ̀rọ ayélujára

Oríṣun àwòrán, @willamazen
Kolawole Ajeyemi, to jẹ ọkọ Toyin Abraham ti sọrọ lori aawọ to waye laarin iyawo rẹ ati ojugba rẹ ninu iṣẹ sinima, Lizzy Anjorin.
Bi ẹko ẹ ko ba gbagbe, lati nkan bi ọsẹ kan sẹyin ni ija kan ti n waye laarin Toyin ati Lizzy lori ẹrọ ayelujara, eyi to ti mu ki Lizzy sọ ọpọlọpọ ọrọ kobakungbe si Toyin.
Ninu erongba ti Kolawole fi lede loju opo Instagram rẹ, ko da ẹnikẹni lẹbi ọrọ naa, ṣugbọn o bu ẹnu atẹ lu bi awọn oṣere naa ṣe n lo ẹrọ ayelujara lọna to lodi.
Ọkọ Toyin ṣalaya pe, laye atijọ nigba ti ohun wọ iṣẹ tiatia, ti ko si ẹrọ ayelujara, awọn eeyan ma n wo awọn ọsere loke ni, ṣugbón laye ode oni, awọn oṣere ko ni iyi mọ.
Kolawole ni awọn oṣere tiata ti awọn eeyan n wo bi aṣaaju ni wọn n gbe ẹtẹ ara wọn sode lori ẹrọ ayelujara, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, kolawoleajeyemi
Bẹẹ lo tun woye pe, ẹka ileeṣẹ sinima agbelewo jẹ ibi ti awọn eeyan ti le kọ ọgbọn, to si yẹ ki awọn osẹre maa lo oju opo ẹrọ ayelujara wọn lati kọ awọn ololufẹ wọn lẹkọ, kii sẹ lati ma ṣi awọn eeyan lọna..
Kọlawọle wa rọ awọn oṣere sinima lati jẹ apẹrẹ rere fun awọn ololufẹ wọn, ati awọn elomiran to n wo wọn loke bi aṣaaju.








