Xenophobia: Ọmọ Naijiria tó lé ní 300 ti dé láti South Africa

Oríṣun àwòrán, @nidcom_gov
Ọmọ Naijiria to le ni ọọdurun ti pada si orilẹede Naijiria lẹyin ti wọn kuro lorilẹede South Africa latari isekupani to waye nibẹ.
Ijọba ilẹ South Africa ti fun ọkọ baalu Air Peace laaye lati ko awọn ọmọ Naijiria to sa asala fun ẹmi wọn.
Lẹyin ọpọlpọ wakati ti awọn eniyan fi duro, ọkọ baalu naa balẹ si papakọ ofurufu ti ipinlẹ Eko ni aago meje kọja.
Laipẹ yii ni Aarẹ orilẹede South Africa, Cyril Ramophosa ti tọrọ afọriji lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lori isekupani awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa.









