EKSU: Bukola gún Jọ́ọ́nù ọ̀rẹ́kúnrin rẹ̀ pa ní Fásitì ìpínlẹ̀ Èkìtì nítorí àìrówó irun san

Abaw#ole Fasiti ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, @ArtsMalo

Ọmọ ileewe Fasiti ipinlẹ Ekiti kan, Bukola Odeyemi, ti gun ololufẹ rẹ pa.

Ọmọ ogun ọdun naa, lo gun ololufẹ rẹ, John Iju, to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun pa, nitori o kuna lati fun un ni ẹgbẹrun meji abọ naira lati fi se irun.

Iroyin sọ wi pe, ọrọ naa ṣẹlẹ ni Iworoko-Ekiti, ni agbegbe ibi ti awọn ọmọ ileewe naa n gbe, ni nkan bi aago mẹwa aṣalẹ.

Ikuna John lati fun Bukọla ni owo irun yii lo da ija nla silẹ laarin wọn, sugbọn ni igba ti ọwọ ologbe ọhun le ju ti Bukọlalọ, lo mu ọbẹ, to si gun ni igba aya.

Awọn oṣoju mi koro ni agbegbe ile igbe awọn awọn ọmọ ileewe naa salaye fun awọn oniroyin pe, lẹyin ti Bukola gun ọrekunrin rẹ yii ni o n da ẹjẹ lara, to si jẹ Ọlọrun nipe loju kan naa.

Awọn ọrẹ oloogbe yii lo fi ọrọ naa to ajọ ọlọpaa leti.

Alukoro awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Caleb Ikechukwu, fi idi ọrọ naa mulẹ, to si sọ wi pe ọwọ ofin ti tẹ afurasi naa, ti iwaadi si ti n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'