Alaafin: Olorì Folashade ní òun ni olorì àkọ́kọ́ tó bí ìbẹta nílẹ̀ Yorùbá

Alaafin ati Olori Folashade

Oríṣun àwòrán, Alaafin_oyo

Àkọlé àwòrán, Olori Folashade sọ pe ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni oun nigba ti oun pade Alaafin

Ọkan pataki lara awọn 'Ẹlẹ Daddy', oxygen ti Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi, fi n mi, ni Olori Aisha Folashade Adeyemi jẹ.

Ọdun 2008 ni iroyin kọkọ gbale-gboko nipa apọnbeporẹ olori naa, lasiko to bi ibẹta lanti-lanti ni ọọdẹ Alaafin.

Iru eyi ko ṣẹlẹ ri ni aafin naa, nitori pe ibeji tabi ọmọ ẹyọ kan ni awọn olori maa n bi latẹyinwa.

Olori naa sọ pe, lẹyin ọdun kẹta ti oun di iyawo alaafin, l'oun to ri ọmọ bi, to si jẹ ibẹta.

Olori Folashade

Oríṣun àwòrán, Alamy

O ni "apẹẹrẹ nla gba a ni awọn ibẹta mi jẹ, nitori pe ibeji ni mo tọrọ lọwọ Ọlọrun, mẹta lo fun mi lẹẹkan naa, lati san ẹsan ọdun mẹta ti mo fi ni idaduro.

"Emi gan-an si ni ayaba akọkọ nilẹ Yoruba to bi ibẹta."

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti iwe iroyin The Nation ṣe fun, Olori Folashade sọ pe, lasiko ti oun wa nileewe olukọni Emmanuel Alayande College of Education, ni oun bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu iku baba yeye, alaṣẹ ekeji orisa.

Ṣe Ọlọrun lo mọ ọkọ iyawo oju ọna, Folashade ni irinajo afẹ fun idanilẹkọ ni oun ati awọn akẹẹgbẹ oun nileewe lọ fun, nigba ti oun kọkọ mọ Alaafin.

Oni lẹyin irinajo naa ni awọn di ọrẹ, ti ọrẹ si pada di tọkọ-taya.

Awon ibeta alaafin ati awọn obi wọn

Oríṣun àwòrán, Alaafin_oyo

O ni o ṣeeṣe ko jẹ lasiko irinajo naa ni Alaafin ti n yofẹ fun oun, nitori pe oun fakọyọ nibẹ nipaṣẹ awọn ibeere ti oun n beere lọwọ baba.

Olori Folashade sọ pe, ẹru kọkọ ba iya oun nigba ti oun sọ fun pe Alaafin ni oun fẹ ẹ fi ṣe ade ori.

O ni ibẹru rẹ naa kuku ye oun, nitori pe ibaṣepọ to wa laarin Alaafin ilu Oyo ati awọn eniyan Isalẹ Oyo nilu naa, ko dan mọran lasiko naa.

Ṣugbọn o, baba rẹ fọwọ si igbeyawo naa pe "to ba jẹ pe fifẹ Alaafin yoo mu Alaafin wọ Isalẹ Oyo, a jẹ pe ko b'ewu de".

Folashade ni a fi bi ẹni pe baba oun sọ asọtẹlẹ ni, nitori pe fifẹ ti oun fẹ Ọba Lamidi Adeyemi, ti pari aawọ to wa laarin rẹ ati awọn eniyan Isalẹ Oyo, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ṣi n binu.

Iru ololufẹ wo ni Alaafin?

Alaafin ati awọn 'Ẹlẹ Daddy' ninu aṣọ ankoo

Oríṣun àwòrán, ayaba_folashade

Àkọlé àwòrán, Alaafin ati awọn 'Ẹlẹ Daddy' ninu aṣọ ankoo

Olori Folashade sọ pe, iroyin ko to afojuba ni ọrọ bi Alaafin ṣe mọ ikẹ ati igẹ obinrin ṣe to. O fikun pe, baba ma n ran oun lọwọ nile idana.

Lori oun to mu ki Alaafin wu lati fi ṣe ọkọ, Olori ni ọlọgbọn ni baba, ọba to yatọ ni, to si tun jẹ ẹni to fẹran iwe kika.

O ni baba n dana ifẹ yá oun ju bi awọn ọdọmọkunrin ṣe le ṣe lọ.

Ayaba Folashade Adeyemi

Oríṣun àwòrán, ayaba_folashade

Ṣe lootọ ni pe Olori Badirat Ajoke ni ajọṣepọ pẹlu KWAM 1?

Lori eyi, Olori Folashade sọ pe iroyin to bani lọkan jẹ pupọ ni iroyin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Iru nkan bẹ ẹ ko ṣẹlẹ rara, irọ patapata ni gbogbo rẹ.

"Mo le fi ògún rẹ gbari pe, Olori Badirat ati King Wasiu Ayinde ko ni ajọṣepọ."

O ṣalaye pe, bi iya ni K-1 ṣe mu gbogbo olori Alaafin, to si ma n pọn wọn le.

Lori ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn olori to ku ni Aafin Oyo, Folashade sọ pe, kii ṣe pe awọn kii ja o, ṣugbọn eto ti wa nilẹ laarin awọn olori lati pari ija naa, lai jẹ pe Alaafin gbọ si.

Àkọlé fídíò, Mistura Oseni Akintunde: Ara múmú kìí ṣe oríṣun ìfipábánilòpọ̀, ìran àwòjù ló ń fà á

Bakan naa lo sọ pe, lootọ ni oun jẹ iyawo nile olorogun, ṣugbọn oun ko le ki awọn ọmọ oun laya lati jẹ olorogun.

"Mi o l'ero pe ma a fẹ oniyawo pupọ, ṣugbọn mo ba ara mi nibẹ.

Mi o fẹ ki awọn ọmọ lọ sile olorogun, ṣugbọn to ba jẹ pe akọsilẹ Ọlọrun ni pe ko ribẹ fun wọn, a jẹ pe yoo dari ẹsẹ wọn."