Road accident: Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan

Oríṣun àwòrán, News Central
Eleduwa ko ni jẹ ki a ṣi rin ni adura tawọn arinrin ajo maa n gba lọna irin ajo. Eeyan mẹjọ ọtọtọ lo jona raurau ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju ọna mọrosẹ ilu Eko si Ibadan lopin ọsẹ yii.
Ọkọ bọọsi Mazda pẹlu nọmba AAA 249 VX ni ijamba naa ṣẹlẹ si lẹgbẹ afara Saapade ni bii aago mẹsan ku iṣẹju mẹẹdogun.
Ọga awọn ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC ti ipinlẹ Ogun, Ahmed Umar lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.
- Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná
- Èèyàn kan kú, ọmọ méjì sọnù nínú òjò tó rọ̀ nílùú Ilorin
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé
- Àwọn agbófinró ti mú Eji tó jẹ́ igbákejì Ebila, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn "One Million Boys" sí gbaga
- Owó wọgbó! Liverpool lu Chelsea lálùmọ́lẹ́ bíi bẹ̀m̀bẹ́
Ọgbẹni Umar ṣalaye pe eeyan mọkanla lo wa ninu ọkọ naa ninu eyi ti mẹjọ ti dero ọrun ti awọn mẹta si mori bọ.
Lọgan ti ọkọ naa gbina lawọn ẹṣọ oju popo pe awọn oṣiṣẹ panapana, amọ ọwọ ti bọ sori ki wọn to de bẹ.
Ajọ ẹṣọ oju popo sọ pe taya ọkọ akero naa lo fọ lori ere ti ọkọ ọhun si bẹrẹ si ni gbe okiti ki o too gbina.
Ọga ajọ ẹṣọ oju popo ni awọn to mori bọ ninu iṣẹlẹ naa si n gba itọju lọwọ nile iwosan to wa ni Sagamu.
Ọga awọn ẹṣọ oju popo wa rọ awọn awakọ lati maa bọwọ fun ofin oju popo ki wọn si maa rii pe taya ọkọ wọn duro deedee.
- Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Ọkùnrin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ǹkan nílé ìjọsìn rí ẹ̀wọ̀n he!
- 'Mo mọ̀ọ́mọ̀ sin ọmọ-ọmọ mi, ìkókó jòjòló láàyè ni, nítorí wọ́n fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ ló fi lóyún rẹ̀'!















