Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mohammed Adamu
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti ju afurasi ọlọpaa kan to yinbọn fun ọdọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun, Ledisi Kote lẹsẹ lori ẹsun pe o fun ọmọdebinrin kan loyun.
Ni ijọba ibilẹ Gokana nipinlẹ Rivers ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Nnamdi Omoni lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin.
- ''Operation Burst'' ti mú Eji olórí ''One Million Boys'' tó gba ipò Ebila
- Ọkùnrin kan tún pa ọmọ rẹ méjì àti ìyá tó bíi
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
- Mo mọ̀ọ́mọ̀ sin ọmọ-ọmọ mi, ìkókó jòjòló láàyè ni, nítorí wọ́n fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ ló fi lóyún rẹ̀!
- Obaseki la Ize-Iyamu mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo
Omoni ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gba ibọn lọwọ ọlọpaa naa, o si ti wa lahamọ ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii awọn ọdaran.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọdọkunrin to yinbọn fun lẹsẹ naa wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju.
Omoni sọ pe ni bi aago meje aarọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ ni ọlọpaa yii ṣadeedee lọ si ile awọn Kote nibi to ti sọ wi pe oun fẹ ri i.
Ọlọpaa yii wọ inu yara Ledisi lọ fun ra rẹ lẹyin ti awọn ẹbi rẹ ko fẹ fi oju rẹ han.
Lẹyin to wọ ọdọkunrin yii sita tan lo dabọn bo o lẹsẹ.
- Trikytee àti Ozo ní wọ́n di ẹrù ilé lé lórí nilé bbnaija lọ́sẹ̀ yìí
- A fẹ́ gbé orò láti lé àwọn ajínigbé kùrò ní ìpínlẹ̀ Oyo- Áṣẹyin ti Iṣẹyin
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Ilé ìjọsìn lè bẹ̀rẹ̀ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ padà, Mọ́sáláṣí àti Ṣọ́ọ̀ṣì lé gba iye èèyàn tó wù wọ́n ṣùgbọ́n...
- Obìnrin bíi Ruth Bader ni yóò gba ipò rẹ́ ní iléẹjọ́ tó gajùlọ nílẹ̀ Amerika- Donald Trump
- Ọkùnrin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ǹkan nílé ìjọsìn rí ẹ̀wọ̀n he!














