US terrorist list: Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Google
Orilẹ-ede Sudan ti ran awọn aṣoju lọ si orilẹ-ede United Arab Emirates lati lọ jiroro pẹlu ilẹ Amerika lori bi wọn yoo ṣe yọ orukọ wọn kuro ninu awọn orilẹ-ede ti wọn n ṣe agbatẹru fun ikọ agbesunmọmi ni agbaye.
Adari orilẹ-ede Sudan, Ọgagun Abdel Fattah al-Burham lo dari ikọ ti wọn lọ fun ijiroro naa.
Ọdun 1993 ni ilẹ Amerika fi orukọ Sudan mọ orilẹ-ede to n sagbatẹru fun ikọ agbẹsunmọmi, lẹyin ti Sudan daabobo Osama Bin Laden to jẹ ọkan lara awọn agbesunmọmi lagbaye fun ọdun marun un.
- Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Àwọn agbófinró ti mú Eji tó jẹ́ igbákejì Ebila, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn "One Million Boys" sí gbaga
- Wo bí odò Nile tó gùn jù l'Áfíríkà, ṣe ń fójúu ilẹ̀ Egypt, Ethiopia àti Sudan han màbo
Lara ohun ti ilẹ Amẹrika beere fun ni ki Sudan san ọọdunrun miliọnu dọla (£232m) gẹgẹ bi owo gba ma binu fun awọn ẹbi ti ikọ agbẹsunmọmi ṣe atako si.

Oríṣun àwòrán, Google
Bakan naa ni orilẹ-ede Amẹrika n beere fun ki Sudan pari ija pẹlu ilẹ Isreal, ki ibaṣepọ si pada si aarin wọn.











