Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Àkọlé fídíò, Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Tọkọ taya tuntun ati oyun inu wọn naa ba iṣẹlẹ naa rin, iyẹn Chisom àti Emmanuel Uyamadu

Ibugbamu ni ipinlẹ Eko ati abajade iwadii ikọ BBC Africa Eye.

Lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹta \, ọdun 2020 lo ṣẹlẹ nibi ti ẹmi eeyan mẹtalelogun ba iṣẹlẹ naa rin.

Ajọ NNPC ni pe kii ṣe ẹbi wọn rara pe afẹfẹ gaasi ati ikọlu to waye lo faa.

Ile iwe Bethlehem Girls College lo fi ara gba iṣẹlẹ naa julọ ni eyi ti ẹmi Arabinrin Heniriatta Alokha sọnu sii to jẹ ọga ile iwe naa

Pẹlu ọpẹ ni awọn eeyan fi n sọ pe ẹmi akẹkọo kankan ko sọnu sinu iṣẹlẹ naa.

Ajọ elepo rọbi Naijiria di ẹbi iṣẹlẹ naa kuro lori wọn ṣugbọn awọn eeyan ni ọpa epo to bẹ lo faa.

BBC Africa ṣe iwadii lori awọn fọnran fidio to jade ati awọn nkan miran lati fidi otitọ ọrọ yii mulẹ pe ọrọ ko ri bi NNPc ṣe sọ lori ibugbamu naa.