Say no to rape: Àwọn òṣèrébìrin Yollywood sọ tiwọn lórí ìfipábánilòpọ̀ tó gbòde

Iyabo Ojo, Mercy Aigbe ati Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn obinrin to jẹ oṣere ni Naijiria ko lee pa ero ti wọn mọra rara pẹlu iwa aburu ifipabanilopọ to gbode kan to si n waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Isẹlẹ yii bẹrẹ ko tii to ọsẹ meji rara bẹẹ si ni laarin ọsẹ meji yii nikan, yatọ fun iye awọn obinrin ti wọn ti fipabalopọ lawọn ipinlẹ kọọkan, kayefi ni iroyin to yi awọn iṣẹlẹ ọhun ka eyi to n kọ awọn araalu lominu.

Aidawọ iṣẹlẹ yii duro lo mu ki awọn eniyan maa figbe sita lati sọ ẹdun ọkan wọn, bi awọn kan ṣe n dabaa ijiya iku, lawọn mii n fi epe ranṣẹ si awọn to n ṣe iru iṣẹ laabi yii kaakiri.

Ẹwẹ, sisa ipa ara ẹni ko yọ awọn oṣerebinrin Yollywood silẹ gẹgẹ bi wọn ṣe tu sita loju opo ayelujara wọn lọkọọkan pẹlu fidio, ọrọ, aworan ati bẹẹ bẹẹ lọ lati lodi si iwa ipa naa.

Iyabo Ojo

Lasiko isede yii, ọpọ awọn ololufẹ awọn oṣere lo tun n wọ lọ si oju opo ayelujara oṣerebinrin Iyabo Ojo pẹlu ọna to n gba da awọn eeyan lara ya ṣugbọn nigba tọrọ ifipabanilopọ bẹrẹ si ni gbode, ọna mii ni Iyabo gba yọ pẹlu fọnran to fi sita ninu aṣọ dudu ati omije loju pe oun to ba ni lọkan jẹ ni ki awọn to yẹ ko maa da abo awọn ọmọde sọ ara wọn di eṣu to n fipabaniopọ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

O ni ta la ba gbẹkẹle nigba ti wọn tun n na ika afurasi i ẹni ti wọn fipa ba lo pọ.

Jaiye Kuti

Lara awọn agba oṣerebinrin ni Jaiye Kuti.

O fi iporuru ọkan sọrọ pe bi obinrin ba niwa rere ko ni ki wọn ma fipa ba a lo pọ, kii ṣe tori obinrin n mu ọti tabi gbe ogun oloro ni wọn fi n fipa ba wọn lo pọ kii si i ṣe tori wọn ko ṣọra ni obinrin fi n ṣagbako ifipabanilopọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ẹwẹ, Jaiye ni iwa aidaa yii ko tọ niwaju eniyan ati Ọlọrun.

Mercy Aigbe

Gbajugbaja oṣerebinrin fi ọpọlọpọ ọrọ ati aworan sita ni ipa tirẹ lati waasu didẹkun iwa ifipabanilopọ.

Ninu ọkan, Mercy fi aworan sita to sọ pe "o lee jẹ iṣẹju marun un fun iwọ (afipabanilopọ) ṣugbọn ayeraiye ni fun oun (ẹni ti wọn fipa ba lo pọ).

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Torinaa o ni ọdaran lawọn afipabanilopọ bi ọdaran si ni ki wọn ṣe fiya jẹ wọn.

Funke Akindele (Jenifa)

Oṣere apanilẹrin nni Jenifa kọ ọ si oju opo instagram rẹ pe gbogbo bo ṣe n lọ yii kan ṣaa su oun.

Ipaniyan! idarudapọ ati iruniloju! iwa ibajẹ! airiṣẹ! gbigbe ninu ibẹrubojo!

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4

O ni ko sẹni to mo ohun to tun kan lẹyin gbogbo eleyii.

Ninu ọrọ mii, adura ni Funke Akindele gba to sọ asọtẹlẹ si oṣu ikẹfa pe ko bi ibukun ko si wẹ gbogbo ọgbẹ wa danu.

Ko mu idajọ wa sori gbogbo awọn aṣebi ko si jẹ ki alafia wa niluu.

Toyin Abraham

Ilumọka oṣere ni Toyin Abraham. O sọrọ gẹgẹ bi iya ati abiyamọ pe oun ko le koju kuro lara iṣẹlẹ yii.

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 5

O ni ọmọbinrin nilo aabo gbogbo wa torinaa ki gbogbo eeyan dide fun ootọ tori pe iṣẹlẹ yii ti su gbogbo obinrin.

Toyin Abraham tun fi nọmba ti awọn obinrin le pe lati fẹjọ ifipabanilopọ sun.

Opeyemi Aiyeola

Aworan ọmọdebinrin ti ẹyin aṣọ rẹ kun fun ẹjẹ ni Opeyemi fi sita lati sọ pe "ọmọdebinrin ni wa, ọdọbinrin ni wa, agba obinrin ni wa, iya ni wa, a nilo idajọ fun awọn ọmọbinrin wa.

Skip Instagram post, 6
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 6

To ba ṣe ọmọbinrin tirẹ n kọ?"