Oniru of Iru land: Onírù tuntun Oba Abdulwasiu Gbolahan Lawal gba ọ̀pá àṣẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu
Oniru ti Iru nipinlẹ Eko, Oba Abdulwasiu Omogbolahan Lawal, Abisogun ll ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Oniru ikẹẹdogun.
Ko tii ju ọjọ mẹta lọ ti awọn afọbajẹ atawọn agbaagba ilu Iru yan an laarin awọn arẹmọ ọba to n du itẹ naa.
Lọjọ keje oṣu kẹfa ọdun 2020 ni gomina Babajide Sanwo-Olu gbe ọpa aṣẹ le e lọwọ gẹgẹ bii Oniru kẹẹdogun ti ilu Iru nipinlẹ Eko.
- Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹ gbọ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
- Òṣèré tíátà míì ń ṣàìsàn láti ọdún kẹta, ó bẹ̀bẹ̀ f'ówó
- Nàìjíríà kò ní olórí, ẹ pín sí ẹlẹ́kùnjẹkùn - Soyinka
- Nǹkan oṣù obìnrin le jáde ní imú tàbí ìdodo yàtọ̀ sí ojú ara - Dókítà
- Oluwo bẹ Ìjọba àpapọ̀ láti ṣe òfin tí yóò mú àdínkù ba ìwà ìfipá báni lòpọ
- Ọjà Ọba ní Akure ni ọwọ́ ọloọ́pàá ti tẹ aláàrùn Covid-19 tó sá kúrò ní ilé àyẹ̀wò – Akeredolu
- Ìdájọ́ ikú ni a fẹ́ fún àwọn afipábánilòpọ̀ - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn
Gomina gba Oniru tuntun nimọran lati jẹ ki alafia tẹsiwaju ni ilu naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Sanwo-Olu ni pẹlu Ọlọlajulọ Ọba Abdulwasiu Ọmọgbọlahan ati Olori rẹ ni ko si ani ani, ọjọ iwaju ilu Iru yoo dara o si nireti at pe gigun ori itẹ Oniru tuntun yii yoo jẹ ibẹrẹ irinajo lọ sinu ọjọ iwaju naa.''
O ṣapejuwe ipo ọba gẹgẹ bi ibi akọkọ ninu ijọba o si ni yoo maa jẹ ọna si ibi nkan ini Naijiria ni gbogbo igba.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni ipo Oniru ṣofo nigba ti Oniru ikẹrinla, Ọba Idowu Oniru filẹ bora bi aṣọ.








